Jose Mourinho: Ijadewa nidije Champions League o jẹ tuntun

Oríṣun àwòrán, PA
Olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United, Jose Mourinho, sọ wipe yiyọ ẹgbẹ na kuro ninu idije Champions League nile ninu awọn ikọ mẹrindinlogun ko jẹ nkan tuntun.
Agbabọọlu Sevilla, Wissam Ben Yedder, lo ba ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Spain gba bọọlu sinu awọn lẹmeji ninu ifẹsẹwọnsẹ ti Sevilla ti jawe olubori ni Old Trafford.
Lati igba ti wọn ti fidirẹmi ni ifẹsẹwọnsẹ idije naa lọdun 2011, ẹẹkan ni United de ipele to kangun si eleyi to kangun si taṣekagba idije naa - ibẹ ni Bayern Munich ti bori Manchester United lọdun 2014.
Olukọni Manchester United to fidirẹmi lẹmẹrin nipele naa ninu idije Champions League sọ wipe: "E mi kọ lero wipe gbigba bọọlu wa ko dara to."
O ṣafikun wipe: "E mi ko kabamọ. Mo sa agbara mi, awọn agbabọọlu naa sa agbara wọn. A gbiyanju, a kuna, bi ere bọọlu ṣe ri yẹn."
Mourinho sọ wipe: "Mo joko lori aga yii lẹmeji ninu idije Champions League lẹyin igba ti mo ku Manchester United yọ kuro [nipele ikọ meridinlogun ikain] nile, ni Old Trafford.
"Lori aga yii pẹlu Porto [lọdun 2004] ati Real Madrid [lọdun 2013], wọn jade lasiko mejeji naa.
"Ko kii ṣe nkan tuntun fun ẹgbẹ agbabọọlu naa."
Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si:












