You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wole Adetiran NYSC Anthem: Wole Adetiran tó kọ orin àdákọ ‘NYSC Anthem’ ti jáde láyé
Wole Adetiran to kọ orin adakọ 'NYSC Anthem' ti jade laye ni ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin.
Baba Adetiran to jẹ ọjọgbọn to kawe gba oye dokita ninu iṣẹ orin kikọ ṣe adakọ orin naa ni ọdun 1984.
Agbẹnusọ fun Baba Adetiran, Olaosebikan lo fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba.
Ki o to di oloogbe, o dubulẹ aisan itọ suga, ẹjẹ riru lati ọdun 2018.
- Òkú obìnrin yìí kan ìlẹ̀kùn pósí gbà-gbà-gbà pé òun ò kú lọ́jọ́ ìsìnkú rẹ̀! Kàyéfì tuntun
- 'Ẹ yẹgi fún un'! Ọkùnrin ẹni ọdún 42 gba ìdájọ́ ikú lẹ́yìn tó pa Ọba aládé l'Ekiti
- Ikú àwọn Sójà tọkọ-taya tí wọ́n gé lórí kò yẹ àwùjọ ọmọ ènìyàn rárá - Ààrẹ́ Buhari
- Leke Adeboye àti ọ̀pọ̀ ọmọ ìjọ RCCG ń ṣèrántí ikú Dare Adeboye lẹ́yìn ọdún kan
Oun ni Ọga Agba olorin patapata 'Music Director' Ijọ mimọ ti Kristi lati ọrun wa 'Celestial Church of Christ' kaakiri agbaye.
Ni ọdun to kọja ni ọga agba Ajọ NYSC ni Naijiria, Ọgagun Shuaibu Ibrahim ṣabẹwọ si, ti o si bu si ẹkun lati fi idunnu rẹ han si abẹwo nla naa.
Ọkan lara awọn ọmọ rẹ to kọ ni orin kikọ ni gbajugbaja olorin Kristẹni, Sola Allyson.
Awọn ololufẹ rẹ paapaa awọn ọmọ Ijọ Celestial Church of Christ kaakiri agbaye ti bẹrẹ si ni ṣe idaro rẹ lori ẹrọ ayelujara.