Dare Adeboye: Ọ̀pọ̀ ọmọ ìjọ RCCG ń ṣèrántí olóògbé Pásítọ̀ náà lẹ́yìn ọdún kan to jáde láyé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Leke Adeboye, to jẹ ọmọ alufaa agba ijọ RCCG, E.A. Adeboye ti kọ ọrọ iranti lati ṣaami si ayajọ ọdun kan ti ẹgbọn rẹ, Dare Adeboye jade laye.

Ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Instagram rẹ, Leke fi aworan Dare lede pẹlu akọle pe "Iranti ọdun kan pẹlu ifẹ lati ọwọ Leke Adeboye."

Lẹyin naa lo kọ akọle "Titi ayeraye ni o wa ninu ọkan wa."

Dare, to jẹ ọmọ kẹta baba Adeboye ku lọjọ kẹrin, oṣu Karun un, ọdun 2021, niluu Eket, ni ipinlẹ Akwa Ibom, nibi ti oun atawọn ẹbi rẹ n gbe.

Oloogbe naa, toun ti iyawo rẹ, Temiloluwa, bi ọmọ mẹta, oun si ni igbakeji oluṣọagutan awọn ọdọ ẹkun naa ṣaaju iku rẹ.

Bi mo ṣe bori ibanujẹ iku ọmọ mi - Adeboye

Lasiko isin "Holy Ghost Service" to waye loṣu to kọja, oluṣọagutan E.A. Adeboye sọrọ nipa bo ṣe bori ibanujẹ iku ọmọ rẹ ọhun.

Gẹgẹ bi ohun ti baba Adeboye sọ, atẹjiṣẹ kan lati ọwọ ọkan lara awọn ọmọ rẹ ninu Oluwa lo tu u ninu lẹyin iṣẹlẹ ọhun.

Ẹni ọgọrin ọdun naa ni oun mọ pe Ọlọrun fẹran oun gidi bo tilẹ jẹ pe oun padanu ọmọ.

Adeboye ni "Nigba ti mo padanu ọmọ mi lọdun 2021, inu mi bajẹ gidi... mo gba atẹjiṣẹ lati ọwọ ọmọ mi kan ninu Oluwa to yi ipo ti mo wa pada."

"Ohun to si fi ranṣẹ si mi naa ni pe Baba, ẹ jẹ ki Ọlọrun gbe yin."

Baba Adeboye ti n tukọ ijọ RCCG bọ lati nnkan bii ogoji ọdun o le diẹ sẹyin.