You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Army couple killed in Imo State: Ààrẹ Buhari kín Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà lẹ́yìn nípa Sójà tọkọ-tiyawo tó kàgbákò ikú lọ́nà ibi ìgbéyàwó ara wọn
Aarẹ Muhammadu Buhari ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko mọ ṣe ṣekupa soja meji kan ni ipilnlẹ̀ Imo.
Awọn agbebọnbọn kan ti ọlọ́pọ́ ṣapejuwe gẹgẹ bii awọn ẹgbẹ to n ja fun ominira awọn Biafra ti awọn iroyin mii si sọ pe wọn ge awọn mejeji lori.
Soja Gloria Matthew ati Audu Linus ti awọn mejeji wa loju ọna wọn lọ fun igbeyawo wọn nilana ibilẹ lọjọ Satide ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ aarẹ, Garba Shehu fi sita, aarẹ Buhari ṣalaye bi wọn ṣe pa awọn ologun naa gẹgẹ aṣa atijọ to ti di apati.
"Lorukọ ijọba ati gbogbo orilẹede Naijiria, aarẹ Muhammadu Buhari n fi ibanikẹdun rẹ han si ileeṣẹ ologun Naijiria ati idile Master Warrant Officer Audu Linus ati iyawo afẹsọna rẹ, Private Gloria Mathew ti wn b lori lẹyin ti awọn agbesunmọmi kọlu wọn".
Atẹjade agbẹnusọ aarẹ naa sọ pe ileeṣẹ ologun fi aridaju han pe awọn ẹgbẹ IPOB lo ṣiṣẹ ibi naa.
"Iwa aidaa si mniyan ni wn tun ṣe si oku awọn sọja naa pẹlu bi wọn ṣe fi fidio wọn sori ayelujara. Aarẹ wa dara pọ mọ awọn ọmọ Naijiria lati kẹdun tọkan tọkan paapaa iwa aburu ti awọn eeyan n hu si awọn agbofinro Naijiria.
Aarẹ ṣapejuwe iṣẹlẹ naa bi eyi ti ko boju mu ti ko si jẹ itẹwọgba lawujọ ati pe ki ofin bori ninu ọrọ yii.
O wa rọ awọn olori ilu kaakiri pe ki wọn sọrọ pẹlu ohun kan ṣoṣo lati lodi si iwa aburu yii.
Bí wọ́n ṣe pa àwọn Sójà méjì tó ń lọ fún ìgbéyàwó ara wọn ní ìlú
Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn agbebọn ṣe ṣekupa awọn ọkọ ati iyawo ti wọn jẹ soja ni Iwọ Oorun - Guusu Naijiria niìnlẹ Imo.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ologun fi sita, o ni awọn soja mejeeji yii, Master Warrant Officer (MWO) Audu Linus to jẹ ajagunfẹyinti ati Private (Pte) Gloria Mathew n rinrinajo lọ si ipinlẹ Imo fun igbeyawo ara wọn nilana ibilẹ nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
Ninu atẹjade kan naa to jade lọjọ Iṣẹgun ọjọ Kẹta oṣu Karun ọdun 2022, wọn ni awọn gbọ nipa iṣẹlẹ yii ni ọgbọnjọ oṣu Kẹrin ọdun 2022.
Wọn ni pe awọn agbebọn naa "ko tilẹ lo ọpọlọ wọn" pẹlu bi wọ́n ṣe ri i pe ijọba ibilẹ Nkwerre ni ọọfisa Gloria ti wa.
Ìròyìn tó ń fò kiri ayélujára ní wọ́n bẹ́ orí wọn ni pé wọ́n sì tún fipá bá obìnrin sójà náà lòpọ̀ àmọ́ àwa kò lè fìdí èyí múlẹ̀.
Wọn da ẹbi ikọlu yii si ori awọn ẹgbẹ ajijagbara fun orilẹede Biafra (IPOB) atawọn ẹgbẹ afara jọ IPOB ti wọn n pe ni Eastern Security Network.
Bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ naa ko tii fesi si iṣẹlẹ yii rara amọ iru ipaniyan bi eyi jẹ ọkan lara ọpọlọpọ to ti waye latọwọ awọn agbebọn ni agbegbe naa.
fun igba diẹ bayii, iha Ila Oorun - Guusu Naijiria ti n foju wina ikọlu awọn agbebọn ti wọn si n foju si awọn nkan amayedẹrun lara bii agọ ọlọpaa atawọn ọgba ẹwọn.
Ki lo ṣẹlẹ nigba ti wọn ṣe ikọlu kẹyin ni ipinlẹ Imo?
Eyi to waye kẹyin nipinlẹ Imo ni ti ijọba ibilẹ Ihitte Uboma nibi ti wọn ti pa ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo, INEC.
Fidio kan to gba ori ayelujara kan nigba naa ṣafihan bi awọn agbebọn ti wọn furasi pe ọmọ ẹgbẹ IPOB niwọn ṣe n kọlu ibudo iforukọsilẹ INEC ti wọn si n da ibẹ ru.
Ijọba orilẹede Naijiria ti ṣaaju gbẹsẹ le gbogbo ipa ẹgbẹ IPOB ti wọn si ti kede wọn gẹgẹ bii agbesunmọmi tori wahala to n ṣẹlẹ lagbegbe naa.
Ẹgbẹ awọn ti awọn eeyan kan ṣa n ṣapejuwe bii "Awọn agbebọn teeyan ko mọ" ti da oniruuru wahala silẹ ni ẹkun Iwọ̀ Oorun - Guusu paapaa laarin ọdun 2020 titi pari ọdun 2021. Bakan naa ni wọn ti tẹsiwaju lọdun 2022 bayii.
Ẹwẹ, nipa iku afẹsọna soja meji naa, Audu Linus ati Gloria Matthew, ileeṣẹ ologun Naijiria ti ni awọn ko ni sinmi titi ọw yoo fi tẹ awọn to wa nidi iṣẹlẹ ọhun.