You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Vaginal Health and Sex: Wo ǹkan 21 tó yẹ kí obìnrin mọ̀ nípa ojú abẹ́ rẹ̀, Vagina
Ọpọlọpọ obinrin ni ko mọ ohun pupọ nipa oju abẹ wọn eleyii ti awọn oloyinbo n pe ni Vagina.
Ni aye ode oni, awọn obinrin miran ko mọ nipa iyatọ to n de ba oju ara ni oṣooṣu, imọtoto ati ẹya ara naa, ti eleyii si ṣọwọn loju wọn.
Awọn onimọ nipa obinrin ti ṣalaye awọn nkan ti yoo ran awọn obinrin lọwọ lati mọ nipa ẹya ara wọn, iyẹn vagina daadaa.
Orukọ abẹ obinrin gẹgẹ bi awọn oloyinbo ṣe n pe ni Vulva, kii ṣe vagina:
Inu ara ni vagina wa, ti o si jẹ egungun bi ẹran to so vulva mọ oju ara obinrin ati ilẹ ọmọ.
Vulva lo yẹ ki awọn eniyan ma a pe e ti wọn ba n sọrọ nipa oju abẹ obinrin to wa ni ita.
Vulva ọhun lo di iru abẹ, clitoris ati oju ile ọmọ papọ.
Ẹya ara Vulva n mu ibalopọ dun ti wọn ba fọwọ kan an:
Oju abẹ obinrin nita ti wọn n pe ni vulva yẹn gan lo ni awọn agbegbe ti o ma n mu ki ibalopọ dun fun obinrin, ti o si ma n mu ki ara obinrin ji pepe ti wọn ba fi ọwọ kan an lasiko ere ibalopọ.
Kii ṣe vagina rẹ lo fi n tọ, bi ko se ibi ti wọn n pe ni Urethra
Urethra lo n gbe itọ lati inu ara bladder wa si ode ara.
Urethra kii ṣe ibi ti awọn ọkunrin ti n tọ lati ori nkan ọmọkunrin wọn:
Eleyi le jẹ iyalnu fun ẹ.
Awọn ọkunrin a maa ṣe ẹyọ gba oju ọmọ nkan ọkunrin.
Awọn obinrin a si maa ṣe ẹyọ gba oju ara wọn to wa lati inu ara wọn.
Lati iwaju de ẹyin, iho alakọkọ a maa gbe itọ jade wọn a si maa pari iṣẹ gba oju nkan ara ọmọ obinrin taa mọ si Vagina to wa loke ile igbẹ wọn.
Irun abẹ obinrin:
Irun abẹ rẹ lo n ṣiṣẹ fun idabobo awọn ẹya ara abẹ paapaa ki kokoro aifojuri ma ba ko wọ ibẹ.
Eleyii ti si mu ki dokita onimọ nipa obinrin, Jen Gunter gba awọn obinrin ni imọran pe ki wọn ṣọra lati ma a fa irun abẹ wọn.
Kii ṣe ohun itiju ki abẹ dun obinrin lasiko ibalopọ:
Ọpọlọpọ obinrin ni kii le sọ jade pe oju abẹ n dun wọn lasiko ibalopọ bi o tilẹ jẹpe kii ṣe ohun to yẹ ko ri bẹẹ.
Amọ o yẹ ki obinrin ti oju abẹ ba n dun lasiko ibalopọ lọ ri dokita rẹ fun itọju.
- Kí ló fa gbas-gbos láàrín àwọn òṣèrébìnrin méjì, Laide Bakare àti Eniola Badmus?
- Wo ǹkan mẹ́ta tó n jẹ́ kí abẹ́ obìnrin má a rùn...
- Ọlọ́run mi ló ní kí n bèèrè fún N310,000 lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ mi láti kó wọn lọ sí ọ̀run - Pásítọ̀ Noah Abraham
- "Ọlọ́pàá ní kí n bọra sílẹ láti mọ bóyá obìnrin ní mí torí mo ní irùngbọ̀n"
- Màálù tó ń mu ọtí bíà láti sanra mú ìbẹ̀rù ẹran jíjẹ bá ọ̀pọ̀ Mùsùlùmí
- ̀̀́Wo ǹkan mẹfà tí o kò mọ nípa ẹyà Coronavirus tuntun....-
Oju abẹ Vagina ma n fọ ara rẹ mọ:
Awọn onimọ ma n gba awọn obinrin ni imọran pe ki wọn ṣọra lati ma a fi ọṣẹ fọ oju abẹ wọn nitori oju abẹ naa ma n fọ ara rẹ mọ pẹlu awọn omi ti o ma n jade ni oju ara.
Lilo ọṣẹ tabi awọn eroja miran lati fi fọ oju ara le fa awọn kokoro aifojuri si ara obinrin
Wo awọn arun ailefojuri ti obinrin le ko lasiko ibalopọ ti o ba lo rọba idaboobo:
Awọn kokoro aifojuri kan wa ti obinrin le kagbako rẹ lasiko ibalopọ bi o tilẹ pe o lo rọba idabobo.
Awọn arun ibalopọ naa ni arun herpes, arun HPV, pubic lice ati molluscum contagiosum.
Awọn arun si maa n waye nitori pe Vulva le kan blocus lasiko ibalopọ eleyii to le fa aisan si ara.
Kii ṣe gbogbo obinrin lo ma n gbadun ibalopọ, ti ọkunrin ba ki nkan ọmọkunrin bọ oju ara rẹ:
Ọpọlọpọ obinrin lo nilo ki ọkunrin ba wọn ṣere tabi fi ọwọ kan oju ara wọn lasiko ibalopo ki ara wọn le ta giri ki wọn si gbadun ibalopọ.
Amọ awọn obinrin miran kii gbadun ibalopọ de ibi gbi ( Climax) lasiko ti ọkunrin ba ki nkan ọmọkunrin bọ oju ara rẹ.
Lilo ororo lati fi pa oju ara lasiko ibalopọ ṣe koko:
Awọn obinrin miran maa n ni iṣoro lasiko ibalopọ bii awọn obinrin ti ko ṣe nnkan oṣu mọ tabi obinrin to n fun ọmọ ni ọyan.
Nitori naa o ṣe pataki lati ripe oju abẹ naa ni ororo lasiko ibalopọ ki ohun gbogbo le lọ deede.
Jẹ ki oju abẹ rẹ sinmi lẹyin ibimọ;
Awọn dokita ti gba obinrin ni imọran wi pe ki wọn ṣọra fun ibalopọ laarin bi ọsẹ mẹrin si mẹfa lẹyin ti wọn ba bimọ ki oju ara le pada si ipo bi o ṣe yẹ.
Igbadun lasiko ibalopọ kii jẹ ki obinrin mọ inira lasiko nkan oṣu oṣooṣu;
Iwadii ni awọn egungun to wa ni agbegbe oju ara naa ma n na daradara ti obinrin ba gbadun ibalopọ daadaa, nitori naa ko ni mọ inira lasiko nkan oṣu.Agba n tara ma n ṣakoba fun oju abẹ obinrin.
Bi obinrin ba ṣe n dagba si, awọn eroja ara to wa ni oju abẹ obinrin ko ni ṣiṣẹ karakara bi ti tẹlẹ mọ.
Bakan naa ni nkan oṣu a duro, awọn eroja to n jẹki obinrin loyun ni kiakia naa yoo dopin, paapaa igbadun lasiko ibalopọ.
Yiya iso lati oju ara n ṣẹlẹ si awọn obinrin.
Bi o tile jẹpe idi lo yẹ ki awọn obinrin fi so, awọn ẹlomiran ma n so lati oju ara.
Eleyii to ṣeeṣe ko jẹ nitori ibalopọ, iloyun, ibimọ abi ki ayipada de ba oju abẹ obinrin.
Oju abẹ obinrin kii run bakan naa
Iwadii fihan pe ọtọọtọ ni oju abẹ obinrin ma n run, eleyii to nii ṣe pẹlu ounjẹ ti wọn n jẹ, aṣọ ti wọn n wọ, ilera ara wọn ati omi abẹ to n jade ni ara wọn ti ko ba ni aisan afojuri bii bacteria.
Omi to n jade loju ara ma n yatọ lati igba de igba
Asiko ni gbogbo nkan fun awọn obinrin.
Asiko ti obinrin ba n ṣe nkan oṣu ma n mu ki ayipada de ba omi oju abẹ obinrin. O ma n funfun ni ibẹrẹ oṣu, ti awọ rẹ si le yii pada kuro ni funfun diẹ to ba ti to asiko ti nkan oṣu obinrin bẹrẹ.
Ere idaraya ''kegel'' ṣe pataki fun obinrin
O dara ki awọn obinrin ṣe ere idaraya paapaa obinrin to ba ṣẹṣẹ bimọ, ere idaraya yii yoo fi aye silẹ fun awọn egungun ara rẹ lati pada si ipo.
O ṣe pataki ki o ṣe idaraya yii lasiko to ba n lọ si ile igbọnsẹ- yoo di oju ara rẹ mu fun igba diẹ, ti yoo si ma a mi bakan naa.
Eleyii yoo jẹ ki oju ara naa ni okun daradara.
Oju ara nilo pH balance 4.5
Fun ọmọbinrin lati loyun, ẹda ọkunrin gbọdọ lọ si inu ara obinrin eleyii ti yoo muu di ọmọ nibẹ.
Ki eleyii file waye, obinrin nilo pH balance 4.5
Ohun atijọ ni ki a fi ọṣẹ fọ abẹ
Awọn oloyinbo ti ni fifọ abẹ iyẹn ''douching'' ma n ṣe akoba fun oju abẹ obinrin ni, ko ni nkan rere kan lati ṣe fun obinrin, aisan lo n fa.
''Orgasm'' lasiko ibalopọ fun obinrin
Kii ṣe gbogbo obinrin lo ma n gbadun ibalopọ de bi gbi, ti awọn oloyinbo n pe ni ''orgasm'' ti wọn a si ''ejaculate.''
Amọ ti o ba n ''ejaculate'' gẹgẹ bi obinrin o ku oriire.
Ti obinrin ba ''ejaculate'', o ma n dabi miliki lo jade ni oju ara ti a si dabi ẹni pe ọrun ni wọn wa nitori igbadun naa, eleyii yatọ si ti obinrin ba n tọ.
Ifarajọra to wa ni nkan ọmọkunrin ati ti obinrin
Awọn onimọ ni o jọ ara daadaa nitori ẹya ara ti wọn jọ ni bii ''frenulum ati prepuce''
Orisirisi ni ẹya oju abẹ obinrin
Oju abẹ obinrin ma n yatọ si ara wọn, bi ti awọn kan ṣe wa ni inu, ni ti awọn miran wa ni ita ti o ṣe tete ri.
Bakan naa ni aworan ati bi o ṣe tobi si yatọ si ara wọn.
- Ìgbà mélòó ló yẹ ko máa pàrọ̀ ‘bedsheet’ rẹ?
- Ẹni tí mo máa gbé ìjọba lé lọ́wọ́ rèé - Ààrẹ Buhari
- Fayemi ní òun ṣetán láti gbéná wojú àwọn alágbára tí kò jẹ́ kí Nàìjíríà tẹ̀síwájú
- Bí wọ́n ṣe pa Sójà méjì tó ń lọ fún ìgbéyàwó ara wọn ní ìlú
- Ọlọ́run mi ló ní kí n bèèrè fún N310,000 lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ mi láti kó wọn lọ sí ọ̀run - Pásítọ̀ Noah Abraham
130 degree ni oju abẹ Vagina wa
Awọn onimo ni idi ni yii ti o ma n dabi ẹni pe awon ọkunrin n kan ẹgbẹ ogiri lasiko ibalopọ laarin ọkunrin ati obinrin.
Obinrin naa ma n ni 'pink balls'
Pink ball tumọ si aibalẹ ara paapaa nkan ọmọkunrin ti ko ba tii ni ibalopọ fun igba pipẹ.
Wọn ni kii ṣe ọkunrin nikan lo n koju rẹ, awọn obinrin naa ni tiwọn ni ara.