Màálù tó ń mu ọtí bíà láti sanra mú ìbẹ̀rù ẹran jíjẹ bá ọ̀pọ̀ Mùsùlùmí

Adari awọn ọlọpaa Hisbah ni ipinlẹ Kano, Sheik Haruna Ibn Sina ti sọ fun awọn Musulumi pe ki wọn mase foya lati jẹ ẹran maalu nitori fidio to ja rainrain lori ẹrọ ayelujara.

Fidio naa lo ṣafihan bi awọn darandaran kan ṣe n bu ọti sinu ike nla fun maalu lati mu, ki o le sanra.

Ninu Fidio naa, ti ọgọọrọ awọn eniyan ti pin si ori ẹrọ ayelujara, ni wọn ti beere lọwọ ẹni to n da ọti naa idi to fi n ṣe bẹẹ.

Darandaran naa wa dahun pe ọti lile yoo mu ki awọn maalu naa sanra si.

Ṣe lọọtọ ni ọti bia n mu maalu sanra?

Gẹgẹ bi awọn eniyan to n ṣe iru iṣẹ yii ṣe ṣọ, wọn ni maalu to ba mu ọti yoo sanra, ti ara rẹ yoo si ji pepe.

Amọ Shelk Ibn Sina sọ ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC pe, awọn ẹlẹsin Musulumi ko ṣẹ si Ọlọrun, ti wọn ba jẹ maalu to mu ọti lile.

‘’Emi naa ri fidio naa bi ọpọlọpọ awọn eniyan se ri i, amọ ko si ẹṣẹ ninu jijẹ ẹran maluu ti o mu ọti.’’

‘’Nitori ọti ti maluu mu tabi ti ewurẹ mu ko le e ran ẹni to ba jẹ ẹ tabi mu miliki rẹ.’’

Onimọ nipa Islam naa ni idi ti oun se fi ẹnu si fidio to n ja ranyin nilẹ naa ni pe, awọn eniyan fẹ mọ otitọ nipa bi iṣẹlẹ ọhun ṣe le ṣakoba fun irinajo wọn gẹgẹ bi Musulumi.

‘’Imọ Sayẹnsi ko fi idi rẹ mulẹ pe maalu to ba mu ọti yoo sanra tabi ji pepe’’

Dokita onimọ nipa itọju awọn ẹranko, Muhammed Sanusi Yahaya lati fasiti ipinlẹ Sokoto sọ fun BBC pe, ko si imọ sayẹnsi to fi idi rẹ mulẹ pe ọti n mu maluu sanra si.

‘’Mo ri fidio naa, amọ ko si imọ ijinlẹ sayẹnsi to fi idi rẹ mulẹ.

‘’Ohun ti a mọ ni pe, maluu to ba jẹun daradaray, to si mu omi daradara, yoo lokun lara, ti yoo si sanra.’’

‘’Lori iwadii boya ẹni to ba jẹ iru ẹran ti wọn fi ọti bọ naa yoo ni ipalara, dokita naa ni ko si ohun to jọ bẹẹ.’’

O ni ọti naa yoo la ‘’mẹtabolism’’ ara maluu kọja, eleyii ti yoo yọ ohun gbogbo to le wu ninu rẹ, ti eyi yoo si mu ki awọn eniyan to ba jẹ wa ni ailewu.

Ọpọlọpọ eniyan kaakiri agbaye lo n jẹ ẹran maluu lati fi ni eroja ‘’protein’’ to n ṣe ara loore, ti ọpọ eniyan to jẹ ẹlẹsin Musulumi si n pa ẹran naa lati fi ṣe ọdun.