Lebanesse crushed lady's leg with car: Ọmọ orílẹ̀èdè Lebanon dèrò àgọ́ ọlọ́pàá l'Eko lẹ́yìn tó fi ọkọ̀ gba obìrin kan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fi ṣikun ofin mu ọmọ orilẹ-ede Lebanon kan, John Greg, lori ẹsun pe o fi ọkọ ayọkẹlẹ rẹ gba ọdọbinrin kan lagbegbe Victoria Island, ipinl Eko.

Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ naa l'Eko, SP Benjami Hundeyin fi lede loju opo Twitter rẹ, o ni lẹyin ti wọn mu okunrin naa, awọn tun ti gbẹsẹle ọkọ rẹ.

Hundeyin ni "Ni nnkan bii aago mẹjọ ku iṣẹ marundinlogun laarọ ọjọ kẹrin, oṣu Karun un, ni ọmọ orilẹ-ede Lebanon naa to n wa ọkọ Toyota 4Runner to n gba 'one way' fi ọkọ gba obinrin kan, Omotomi Akinsanya, eyii to to mu ko farapa yanayana lẹsẹ rẹ."

"Okunrin naa salọ lẹyin iṣẹlẹ naa amọ a le lere, a si ti fi ṣikun ofin mu. Afurasi naa ti wa akata wa bayii."

"Obinrin to farapa naa ti wa nile iwosan LASUTH, nibi to ti n gba itọju lọwọ, a ti fi ọrọ naa to awọn mọlẹbi rẹ leti, a tun ti fi ọrọ naa to ọọfisi ijọba orilẹ-ede Lebanon leti, a si ti bẹrẹ iwadii."

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye

Okunrin kan, @wellzpapi lo kọkọ kede ijamba ọkọ naa loju opo Twitter rẹ lọjọbọ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, afurasi naa n wa ọkọ rẹ lagbegbe Victoria Island l'Eko, o si n sare asapajude gba ọna 'one way' titi to fi gba obinrin ọhun.

O ni ọpọ awọn eeyan lo sa asala fun ẹmi wọn lasiko ti afurasi naa fi ọkọ gba obinrin naa.

Wellzpapi ṣalaye siwaju si pe okunrin kan to wa lori alupupu lo le afurasi naa mu ki wọn to fa le awọn ọlọpaa lọwọ.

Ẹwẹ, iroyin ni, Omotola ti n gba itọju lọwọ lẹyin ti wọn ṣiṣẹ abẹ oni wakati meje fun.

Ẹlomiran to sunmọ obinrin naa sọ pe dokita to ṣetọju rẹ ko sọ boya ni ṣe ni wọn yoo ge ẹsẹ rẹ abi bẹẹ kọ nitori wọn ko tii sọ ohunkohun fun awọn mọlẹbi rẹ lẹyin iṣẹ abẹ naa.