You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Abba Kyari: Adájọ́ pàṣẹ kí wọ́n ó gbé Abba Kyari lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje ní Abuja
Ilé-ẹjọ́ giga ti ijọba apapọ to wa niluu Abuja, ti pasẹ pe ki wọn maa gbe Abba Kyari to jẹ igbakeji kọmisọna ti wọn gba isẹ́ lọwọ rẹ lori ẹ̀sùn gbígbé òògùn olóró lọ si ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje to wa niluu Abuja.
Àjọ NDLEA fi ẹ̀sùn gbigbe oogun oloro kokeni (cocaine) kan DCP Abba Kyari ati awọn ọmọ lẹyin rẹ mẹrin pe wọn lọwọ ninu oogun oloro ti ìwọǹ rẹ to 21.25kg, ti ajọ NDLEA gba lọwọ eeyan meji, Umeibe ati Ezenwanne.
Adajọ àgbà, Emeka Nwite lo pasẹ yii pe ki ajọ tó n gbogun ti mimu ati gbigbe oogun oloro, iyẹn NDLEA maa gbe Abba Kyari lọ si ọgbà ẹ̀wọ̀n to wa ni Kuje, lẹyin ti adajọ kọ̀láti gba beeli rẹ, ko le ma a gba ile rẹ wa a jẹjọ.
Ile-ẹjọ tun fi kún un pe àwọn ẹ̀rí to wa niwaju wọn nipa Abba Kyari ko lee jẹ ki wọn gba beeli oun ati awọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ACP Sunday Uba, Inspector Simon Agirgba ati Isipẹtọ John Nuhu.
- Ẹ dákun ẹ má kó wa lọ sẹ́wọ̀n! - Abba Kyari
- Sé Nàìjíríà le fi Abba Kyari ráńṣẹ́ sí Amẹ́ríkà pẹ̀lú bó ṣe ń kojú ìgbẹ́jọ́ àjọ NDLEA? – Àlàyé rèé
- Òògùn lílò àti àwọn nkan mìí tó le mú kí nkan oṣù obìnrin dáwọ́ dúró láìpé ọjọ́
- Ìyáwó Abba Kyari dákú nílé ẹjọ́ bí adájọ́ ṣe kọ̀ láti gba béèlì ọkọ rẹ̀
- Ẹ fura o! Ètò ààbò Nàìjíríà ti ń dàbí ti Afghanistan - Afenifere lọgun
- Agbẹjọ́rò mi yóò tẹsẹ̀ òfin bọ ìṣẹ̀lẹ̀ Shoprite àmọ́ àwọn aláṣẹ ibùdó ìtajà náà sì ń bẹ̀ mí lọ́wọ́ - Toyin Asewo to re Mecca
Amọsa, Onidajọ Nwite pasẹ pe ki awọn agbẹjọro ijọba ati agbẹjọro fun Kyari tètè se kiakia lori igbẹjọ ọhun , botilẹ jẹ pe ilé- ẹjọ ́tún sún ìgbẹ́jọ́ naa si ọjọ́ kejidinlọgbọn, osu kẹrin, ọdun 2022.
Ti a o ba gbagbe pe, Umeibe ati Ezenwanne , ti wọn wa lara awọn ti ajọ NDLEA gbe wa pẹlu Abba Kyari wa sile ẹjọ́ , tí awọn mejeeji si sọ fun ile-ẹjọ pe awọn jẹ̀bi ẹsun ti ajọ NDLEA fi kan wọn.
Oṣu Keji, ọdun yii ni ajọ NDLEA mu Kyari , lẹyin asiko diẹ ti wọn kede pe awọn n wa.
Yatọ si igbẹjọ to n waye lọwọlọwọ, Kyari tun ni ẹjọ ni ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ nilẹ America, fun ẹsun pe o ni ibaṣepọ pẹlu gbajumọ onijibi, Hushpuppi, to ti wa ni ẹwọn nilẹ America bayii.