You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Abba Kyari Update: Sé Nàìjíríà le fi Abba Kyari ráńṣẹ́ sí Amẹ́ríkà pẹ̀lú bó ṣe ń kojú ìgbẹ́jọ́ àjọ NDLEA? – Àlàyé rèé
Èròńgbà ìjọba àpapọ̀ láti fi igbákejì Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá, Abba Kyari ráńṣẹ́ sí ilẹ̀ Amẹ́ríkà láti lọ kojú ìgbẹ́jọ́ tí orílẹ̀ náà ló ṣeéṣe kó má wáyé ní kíákíá.
Èyí kò ṣẹ̀yìn bí ẹ̀sùn ìgbẹ́jọ́ gbígbé egbògi olóró tí Abba Kyari ń kojú níwájú ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tí àjọ NDLEA fi kàn án.
Láti ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì, ọdún 2022 ni Kyari ti wà ní àhámọ́ àjọ NDLEA fẹ́sùn pé ó ń gbèrò láti ta egbògi olóró "cocaine" oní kìlógíràmù mẹ́ẹ̀dọ́gbọ́n léyìí tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn oníṣòwò rẹ̀ kan.
Bákan náà ni àjọ NDLEA tún fẹ̀sùn kàn án pé oníṣẹ́ gbígbé egbògi olóró ni Abba Kyari fún ra rẹ̀.
- Àjọ̀dún Lisabi Agbongbo Akala tọdún 2022 ti bẹ̀rẹ̀ ní Abeokuta
- Ibá Lassa fojú hàn ní ìpínlẹ̀ Oyo, ó ti mú ẹ̀mí Dókítà méjì lọ
- Bàbá Adesola Adedeji, ọ̀kan lára àwọn afurasí méje ń fẹ́ rọ́pò ọmọ rẹ̀ nínú ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke
- Ibá Lassa fojú hàn ní ìpínlẹ̀ Oyo, ó ti mú ẹ̀mí Dókítà méjì lọ
- Kíni àjọ ECOWAS ilẹ̀ Adúláwọ̀ ń sọ báyìí lórí ìjà Russia àti Ukraine?
- Òní ní Baba Ijesha tún fojú ba iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn bíbá ọmọdé lòpọ̀
- Ìdí tí mo ṣe fẹ́ yọ ayédèrú ìdí ńlá tí mo ní- Sophie
- Ọmọ ọdún 15 tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó bá ọmọ ọdún mẹ́jọ lòpọ̀ fojú balé ẹjọ́ l'Eko
- Ilé ẹjọ́ fi Rahman Adedoyin pamọ́ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n bí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ṣe bẹ̀rẹ̀ l'Osun
NDLEA yóò fojú Abba Kyari ba ilé ẹjọ́
Ní àná ni Mínísítà fún ètò ìdájọ́ àti agbẹjọ́rò àgbà orílẹ̀ èdè yìí, Abubakar Malami fi síta pé ìjọba àpapọ̀ ti gbà láti fi Abba Kyari ráńṣẹ́ sí Amẹ́ríkà láti lọ kojú ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ṣíṣe èrú owó tó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú Hushpuppi.
Ẹ̀wẹ̀, lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí àjọ Malami fi ìkéde yìí síta ni àjọ NDLEA náà ní fi ìròyìn síta pé àwọn ti pe ẹjọ́ oní ẹ̀sùn mẹ́sàn-án tako Abba Kyari ní ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ àti pé yóò fojú ba ilé ẹjọ́ lọ́jọ́ Ajé ọjọ́ keje, oṣù kẹta.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí adarí ẹ̀ka àtò òfin àjọ NDLEA, Joseph Sunday buwọ́lù lórí ẹ̀rọ Twitter ní Abba Kyari àti àwọn ọlọ́pàá mẹ́fà mìíràn ni yóò máa fojú ba ilé ẹjọ́ lọ́jọ́ Ajé.
Àwọn ọlọ́pàá tí yóò kojú ìgbẹ́jọ́ pẹ̀lú Abba Kyari ni Sunday Ubua, Bawa James, Simon Agirigba, John Nuhu, Chibuinna Patrick Umeibe àti Emeka Alphonsus Ezenwanne.
Kíni èrò àwọn Agbẹjọ́rò?
Nínú ìfọ̀rọ̀wérò iléeṣẹ́ ìròyìn Punch pẹ̀lú àwọn agbẹjọ́rò, àgbà ọ̀jẹ̀ agbẹjọ́rò kan, Yomi Aliyu (SAN) ní ó ṣeéṣe kí ìgbẹ́jọ́ tí àjọ NDLEA pè tako Abba Kyari ṣe ìdádúró fífi Kyari ráńṣẹ́ sí orílẹ̀ Amẹ́ríkà láti lọ kojú igbẹ́jọ́ lọ́hùn ún.
Aliyu fi kun pé tí ilé ẹjọ́ Nàìjíríà bá dà ní ẹ̀bi, ò dí dandan kó parí ìjìyà tí wọ́n bá fún un kó tó le lọ kojú ìgbẹ́jọ́ ní ilẹ́ òkèrè.
Bákan náà ló ní ìjọba àpapọ̀ tún ní àṣẹ láti kọ̀wé ráńṣẹ́ sí ilẹ̀ Amẹ́ríkà láti bèrè kí Kyari kojú ẹ̀sùn rẹ̀ ní Nàìjíríà nígbà tó jẹ́ pé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni ló ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ tó fẹ́ kojú ìjìyà lé lórí.
Agbẹjọ́rò tó tún sọ̀rọ̀, Ebun-Olu Adegboruwa ní ọgbọ́n àti má jẹ̀ kí Kyari kojú ẹ̀sùn ní Amẹ́ríkà ni ìjọba ṣe ka ẹ̀sùn tuntun náà si lẹ́sẹ̀.
Adegboruwa ní níwọ̀n ìgbà tí Abba Kyari bá ń kojú ìgbẹ́jọ́ ní ilẹ̀ yìí kò lè lọ sí òkè òkun àti pé ọ̀gá àgbà àjọ ọlọ́pàá ń lọ́ tìkọ̀ láti ṣèwádìí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Kyari láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fẹ́ lé Abba Kyari lẹ́nu iṣẹ́:
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Punch ṣe wí àjọ ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ Kyari kúró lẹ́nu iṣẹ́ látàrí gbogbo àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi ń kàn án.
Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn oṣù kan tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní kí wọ́n já ìràwọ̀ rẹ̀ wálẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ fún lílọ́wọ́ nínú ìwà ọ̀daràn tó ní ṣe pẹ̀lú Hushpuppi.
Ìjọba Nàìjíríà ti buwọ́lu ìbéèrè orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà láti fi ọ̀gá ọlọ́pàá Abba Kyari ráńṣẹ́ sí orílẹ̀ èdè náà láti lọ kojú ìgbẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu tí wọ́n fi kàn án.
Amẹ́ríkà ló ti ṣaájú bèrè fún àṣẹ ìjọba àpapọ̀ láti fi Abba kyari ráńṣẹ́ kò lé kojú ìgbẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn jíjí owó mílíọ̀nù lé ọwọ́ kan dọ́là lórí ẹ̀rọ ayélujára.
Kyari ni orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà fẹ̀sùn kàn pé ó lẹ̀dí àpòpọ̀ pẹ̀lú Ramon Abass tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Hushpuppi àti àwọn mẹ́rin mìíràń láti jí owó náà kó.
Mínísítà fétò ìdájọ́ àti Agbẹjọ́rò àgbà orílẹ̀ èdè yìí, Abubakar Malami lo fi ọ̀rọ̀ yìí léde nínú ẹjọ́ kan tó pè síwájú adájọ́ àgbà ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja.
- MC Oluomo, ilá rẹ fẹ́ máa ga ju onírè lọ - NURTW
- Ìdí tí mi ò fi kópa níbi ìpàdé ìpẹ̀tùsááwọ̀ láàárín èmi àti Aregbesola nìyìí – Tinubu
- Àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní Ukraine yóò máa dé láti òní lọ- Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè
- Wo iye èèyàn Ukraine àti àjòjì tó ti kú láti ìgbà tí Russia ti gbógun ti Ukriane
- Ṣé lóòtọ́ ni pé Russia yóò kógun ja Naijiria àti pé ọmodébìnrin Ukraine gbéná wojú ọmọ ogun Russia?
- Àwọn obìnrin bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de lẹ̀yìn tí àwọn aṣòfin kọ̀ láti buwọ́lù òfin tí yóò ṣe wọ́n láàfàní
- Ìlù ti yí, orin ti séńjì! Ẹni tí yóò jẹ Olubadan yóò ní àmúyẹ tuntun - Ìgbìmọ̀ Olubadan
Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?
Malami ni ẹjọ́ náà jẹ́ pípè ní ìdáhùn sí ìbéèrè aṣojú ilẹ̀ Amẹ́ríkà sí Nàìjíríà láti gba orílẹ̀ èdè náà láàyè láti ṣe ìgbẹ́jọ́ Abba Kyari.
Òṣìṣẹ́ àjọ aṣèwádìí ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Andrew Innocenti ti fẹ̀sùn kan pé Hushpuppi gbéṣẹ́ fún Kyari lẹ́yìn ti ẹni kan, Chibuzo Vincent dúnkokò láti tú àṣírí èrú owó mílíọ̀nù lé ọwọ́ kan dọ́là owó oníṣòwò kan tó jẹ́ ará ilẹ̀ Qatar.
Innocenti ní òun ní àwọn ẹ̀rí tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Abba Kyari gba owó mílíọ̀nù mẹ́jọ náírà lọ́wọ́ Hushpuppi láti fi nawọ́ gán àti jíju Vincent sí àhámọ́.
Láti inú oṣù kẹrin ọdún tó kọjá ni ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti ní kí FBI nawọ́ gán Kyari.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kyari jìyàn gbogbo ẹ̀sùn yìí, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti ní kó lọ rọ́kún nílé títí wọn yóò fi parí ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Abba Kyari tún ń kojú ẹ̀sùn gbígbé egbògi olóró
Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn ni Abba Kyari tún kó sí wàhálà tuntun mìíràn nígbà tí àjọ NDLEA fẹ̀sùn kàn án pé ó lọ́wọ́ nínú bí egbògi olóró ṣe wọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti orílẹ̀ èdè Brazil.
Lọ́sẹ̀ tó kọjá, ilé ẹjọ́ kan dá ẹjọ́ pé kí NDLEA fi sí àhámọ́ fún ọjọ́ mẹ́rìnlá.