HIV vaginal ring: Mọ̀ síi nípa òruka ojú ara òbinrin tó le kó ọ yọ lọ́wọ́ HIV

Odu ni aarun HIV l'agbaaye, kii ṣe aimọ fun oloko.

Lati asiko ti aarun naa si ti wa ni awọn onimọ ijinlẹ ti n wa ọna lati dena kiko.

Lara igbesẹ ti wọn ti gbe ni ṣiṣe rọba idaabobo, ti a tun mọ si kọndọmu, fun ọkunrin ati obinrin.

Bakan naa ni oogun wa lati din agbara rẹ ku lara awọn to ba ni i.

Ni bayii, oruka kan tun ni ọna abayọ ti awọn onimọ sayẹnsi ṣe fun idena HIV laarin awọn obirnin.

Wọn ṣe oruka oju ara naa lati le mu adinku ba ewu kiko aarun HIV.

Botilẹ jẹ pe o ti to ọdun diẹ ti oruka naa ti wa nita, awọn orilẹ-ede ilẹ Afirika to ti n lo ko pọ rara.

Lọwọlọwọ, orilẹ-ede South Africa ti buwọlu lilo rẹ

Eyi jẹ igbesẹ pataki, fun orilẹ-ede naa nitori pe ida meji ninu mẹta awọn to ṣẹṣẹ n ni HIV lo jẹ obinrin.

Orilẹ-ede Zimbabwe lo kọkọ fọwọ si lilo oruka yii lọdun to kọja, ọpọ orilẹ-ede nilẹ Afirika lo si ti n ṣe agbeyẹwo rẹ.

Oruka yii lo jẹ akọkọ iru rẹ, to ni agbara lati dena HIV fun igba pipẹ.

Awọn nkan to ṣe koko lati mọ nipa oruka yii

Awọn obinrin nikan si ni wọn ṣe e fun.

Oruka yii ti wọn fi eroja bii rọba, 'silicon' ṣe, ni awọn oogun to n dena HIV ninu.

Oju ara (nibi ti obinrin n gba ni ibalopọ) ni wọn ma n kii si. Eyi to tumọ si pe ọkunrin ko le mọ to ba wa ninu ara rẹ.

Diẹdiẹ lo ma n ṣiṣẹ, pẹlu bi eroja to n dena Hiv, Antiretroviral dapivirine, yoo ṣe ma a jade diẹdiẹ sinu oju ara.

Oṣooṣu si ni wọn o ma a paarọ rẹ.

Kini awọn onimọ sọ nipa rẹ?

Dokita Annalene Nel, to jẹ olori awọn onimọ to n ṣe agbeyẹwo oruka naa ni Malawi sọ pe awọn obinrin le fi sinu oju ara lai si iranlọwọ ẹnikẹni, ti nkan ọmọkunrin ololufẹ wọn ko si ni kan.

Iwadii fihan pe oruka naa n daabo bo obinrin kan ninu mẹta lọwọ HIV.

Dokita Annalene ṣalaye pe oruka yii le jẹ ọna abayọ kan ṣoṣo, paapaa fun awọn obinrin ti ko le kọ ibalopọ pẹlu ọkunrin ti ko lo ọra idaabobo.

Bakan naa lo sọ pe awọn ewu to wa ninu lilo oruka naa, kere pupọ si anfaani lilo rẹ nitori imọ ijinlẹ sayẹnsi ti wọn fi ṣe e.