Oluwo of Iwo wedding: Taa ni Firdauz Abdullahi, ọmọbabìnrin Kano, olòrì tuntun tó ń wọ Ààfin Oluwo lónìí?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oluwo ti Iwo, Oba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti ṣetan lati tun gbe olori tuntun wọ aafin ilu Iwo.

Yoruba ni ti ẹṣin ba da ni, aa tun gun ni.

Bẹẹ gan lo ri fun ọba alaye yii to tun fẹẹ dan igbeyawo wo lẹyin ti igbeyawo rẹ akọkọ tuka.

Gbogbo ilu Iwo lo ti n rọ kẹkẹ bayii, BBC Yoruba gan ti wa nikalẹ.

Oṣu Kejila, ọdun 2019 ni igbeyawo Oluwo ati ọmọ orilẹ-ede Jamaica kan, Chanel Chin tuka, lẹyin ọdun ti wọn di tọkọtaya.

Ọmọkunrin kan, Oduduwa, ni wọn bi fun ara wọn ninu igbeyawo naa.

Lati ọdun 2019 yii si ni Oluwo ti wa lai ni olori laafin.

Iroyin si ti jade sori ayelujara ni awọn asiko kan pe o fẹ fẹ iyawo.

Lara iru iroyin bẹẹ ni aworan kan ti oun ati gbajugbaja akọrin takasufe, Tiwa Savage jọ ya.

Nibi ayẹyẹ orin ti Naira Marley ṣe ni wọn ti ya a.

Akori ti Oluwo kọ si ori aworan naa to fi sori ayelujara Instagram rẹ ni pe o wa ni ikapa oun lati gbẹsẹ le Tiwa ko di olori, to si beere lọwọ awọn ololufẹ rẹ pe ṣe ki oun ṣe bẹẹ.

Ọpọ eeyan lo n sọ nigba naa pe ṣe Kabiesi fẹẹ fi Tiwa ṣe olori tuntun ni, paapaa boṣe jẹ pe igbeyawo Tiwa naa ti tuka.

Bi awọn eeyan ṣe tun n gbe iroyin kiri, ti wọn si tun n beere pe sẹ oun ni Oluwo fẹẹ fẹ ni Jumoke fi ikede sita pe oun kan lọ ba wọn kopa nibi ayẹyẹ ọdun ibilẹ to waye nilu Iwo ni.

'Oluwo kọ lẹta si ijọba Osun fun iranlọwọ owo lori ayẹyẹ igbeyawo'

Tẹẹ o ba gbagbe, ọsẹ diẹ sẹyin ni lẹta kan lu si ori ayelujara, eyi to ṣafihan pe Oluwo n beere fun iranlọwọ ogun miliọnu Naira lati ọwọ ijọba ipinlẹ Osun fun ayẹyẹ igbeyawo to fẹẹ sẹ.

Asiko naa si ni igba akọkọ ti aṣiri igbeyawo tuntun yii tu sita, botilẹ jẹ pe Oluwo sọ pe kii sẹ aafin oun ni lẹta naa ti jade.

Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Osun sọ pe ayederu ni lẹta naa. Wọn ni ọna lati da wahala silẹ laarin ara ilu ati ijọba ni.

Taa ni Firdauz Abdullahi to fẹ di olori tuntun ni aafin ilu Iwo?

Ọmọ bibi ilu Kano, ni Ariwa Naijiria, ni Omidan Firdauz Abdullahi.

Ọmọ ọmọ Emir ilu Kano to ku lọdun diẹ sẹyin, Ado Bayero si lo jẹ.

Eyi to tumọ si pe ibatan Emir ilu Kano lọwọlọwọ ni.

Iroyin sọ pe ọmọbinrin naa ti pe ẹni bi ọdun mẹtadinlọgbọn, gẹgẹ bi iwe iroyin Premium times ṣe sọ.

Ninu ikede igbeyawo naa ti Oluwo funra rẹ fi sita, o ṣapejuwe Firdauz gẹgẹ bi iyawo rere lọọdẹ ọkọ, obinrin to ṣe e kowole, ọmọ ọbabinrin to gba ẹkọ.

O ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun igbesẹ tuntun yii.

Bawo ni eto ati ayẹyẹ igbeyawo naa yoo ṣe lọ?

Ọjọ Satide, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2022 ni igbeyawo naa yoo waye.

Iwe ipe sibi ayẹyẹ naa fihan pe ni ile Madakin Kano, nilu Kano ni igbeyawo naa yoo ti waye.

Lẹyin naa ni apejẹ yoo waye fun awọn ọdọmọbinrin nikan ni aafin Emir ilu Kano, Alhaji Aminu Ado Bayero.

Sugbọn a ko ti i le sọ boya Oluwo funra rẹ yoo wa nibi ayẹyẹ igbeyawo naa.

Eyi ko ṣẹyin aṣa Yoruba to fi lelẹ pe wọn ma n gbe iyawo wa a aba ọba ni aafin rẹ ni.