You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Oluwo Divorce: Ìdí tí Oluwo fi kọ Olorì rẹ̀ sílẹ̀ rèé...
Kabiesi Oluwo ti ilu Iwo, Oba Abdulrosheed Adewale ti kọ olori rẹ Chanel Chin silẹ.
Agbẹnusọ fun Kabiesi ọhun, Alli Ibrahim fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC.
Bo tilẹ jẹ pe Kabiesi ni wọn kọ ara wọn silẹ lataari awọn iyatọ to wa laarin wọn ti ko ṣee yanju.
Oluwo ko sọ ni pato ohun to fa ikọsilẹ naa lasiko yii ju pe ki awọn eeyan dẹkun bibu ọla fun Channel gẹgẹ bii iyawo oun mọ.
Ọmọ kan ni Chanel bí fún Oluwo, orukọ rẹ a si maa jẹ Oduduwa.
Olori Chanel Chin jẹ ọmọ orilẹ-ede Jamaica, baba rẹ si ni olorin takasufe ti ọpọ eeyan mọ si "Bobo Zaro."
Oluwo ṣalaye pe, ikọsilẹ naa ko ṣẹyin pe ọrọ awọn mejeeji ko ye ara wọn mọ
Ati pe ẹnikẹni ko gbọdọ ba olori Chanel Chin tẹlẹ dowopọ mọ lorukọ Olori Oluwo ti ilẹ Iwo, Oba Telu1.