You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kogi murder: Àwọn agbébọn ṣekúpa akẹ́kọ̀ọ́ tó wà nípele àṣekágbá ní fásítì Kogi
Awọn agbebọn ti sẹkupa akẹkọọ fasiti ipinlẹ Kogi kan, Apey Joseph niluu Ayingba.
Ile iṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa ṣalaye pe ipele aṣekagba ni akẹkọọ naa wa lẹka ẹkọ ede Gẹẹsi, ati pe afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ni.
Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa, DSP William Aya fidi rẹ mulẹ pe, akẹkọọ ọhun lo ṣagbatẹru iṣẹlẹ iṣekupani to waye loṣu to lọ ninu ọgba ile iwe naa.
Ile iṣẹ ni ọkan lara awọn ẹṣọ ile iwe naa, Onuche Jibrin lo ta ile iṣẹ ọlọpaa lolobo pe awọn agbebọn meji ti wọn gun ọkada wọ ile iwe naa ti ṣekupa akẹkọọ kan.
Lati ibẹ ni wọn ti gbe akẹkọọ naa digbadigba lọ si ile ẹkọ iwosan fasiti ọhun, ṣugbọn ọwọ ti bọ sori ki wọn to gbe de bẹ.
Agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa tun fidi rẹ mulẹ pe wọn ti gbe oku akẹkọọ naa lọ si ile igbokusi fun ayẹwo.