Omoyele Sowore: Falana ní ìjọba fẹ́ fẹ̀sùn ìgbésúnmọ̀mí kan Sowore

Gbajugbaja agbẹjẹro ati ajafẹtọ, Femi Falana ti ke gbajare pe ijọba apapọ n gbero lati fi ẹsun igbesunmọmi kan Omoyele Ṣowore to ṣagbatẹru iwọde #RevolutionNow.

Ajọ DSS ti kọkọ fi Ṣowore silẹ lahamọ lọsẹ to lọ lẹyin aṣẹ Adajọ Ijeoma Ojukwu, amọ lẹyin ọjọ kan ni wọn tun fi mu u pada.

Ọpọ lo koro oju si igbesẹ ajọ DSS lori ọrọ Ṣowore, ti wọn si di ẹbi gbogbo ẹ ru ijọba apapọ pe o huwa bi i ijọiba afipa muni sin.

Amọ, oludamọran agba si Aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu ni ijọba apapọ kọ lo ran ajọ DSS ni ohun ti wọn n ṣe.

Shehu ni ohun ti Ṣowore ṣe da bi ohun tawọn ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram n ṣe nitori wọn n da rogbodiyan silẹ lapa ariwa Naijiria loke ọya.

Ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aje, agbẹjọro Ṣowore, Falana ṣalaye pe ijọba fẹ fi ẹsun igbesunmọmi kan Ṣowore lẹyin to ti kuna lati fẹsun idoju ijọba bolẹ ati sisọ ọrọ odi kan an.

O ni eyi ko yatọ si ohun ti ijọba ṣe si Nanamdi Kanu ti Ipob iran Igbo.

Falana ni fifi Ṣowore we Boko Hram tumọ si pe ijọba fẹ fẹsun igbesunmọmi kan Ṣowore.

Agbẹjọro Falana ṣalaye siwaju sii pe ijọba mọ pe ile ẹjọ ko ni gba oniduro Ṣowore ti wọn ba le fi ẹsun igbesumọmi kan an.

O kepe ijọba pe ko bẹrẹ igbẹjọ lori ọrọ Ṣowore to ba daa loju pe Ṣowore jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an ni tootọọ.