FIRS: Buhari fi orúkọ àwọn ilé ìgbímọ̀ FIRS tuntun ránṣẹ́ sí àwọn aṣòfin

Aarẹ Buhari to lagbara lati yan ẹnikéni to wuu gẹgẹ bii alaga ajọ FIRS to ba ti gba ifọwọsi awọn aṣofin ti ṣe bẹẹ.

O kede Muhammed Nami to jẹ olugbaninimọran lori ọrọ owo ori gẹgẹ bi alaga tuntun ni kete tile igbimọ aṣofin agba ni abuja ba ti buwọ luu.

Ta ni Muhammed Nami to gba ipò Babatunde Fowler ni FIRS?

O to ọgbọn ọdun bayii ti Muhammed Nami ti n ṣiṣẹ kaakiri ẹka idokowo, iṣakoso owo ori ati ilanilọyẹ lori ọrọ owo ori.

Bakan naa lo tun ti ṣiṣẹ nile ifowopamọ ati ni ẹka ijọba nipa jijẹ olubadamọran ati olugbaniniyanju lori ọrọ okowo ati owo ori.

Nami jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa okowo tuntun ati ọna idagbasoke ninu ọna itaja.

Nibo ni Muhammed Nami ti kawe?

Muhammed kawe jade gboye ẹkọ nipa awujọ lọdun 1991 ni fasiti Bayero ni Kano.

O gba oye imọ ijinlẹ keji ni fasiti Ahmadu Bello to wa ni Zaria nibi to ti kẹkọọ nipa okowo lọdun 2004.

O jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa iṣakoso nipa owo ori ati igbani niyanju ni Kaduna, Abuja ati ipinlẹ Niger.

Ogbeni Nami jẹ alaga fun ọpọlọpọ ile iṣẹ ati idokowo nlanla.

Wọn yan an ni ọmọ igbimọ ileeṣẹ Aarẹ Lori gbigba awọn ohun ini Naijiria ti awọn kan ti jigbe loṣu kọkanla, ọdun 2017.

Muhammed ni iyawo, o si ṣabiyamọ.

Oun ni Aarẹ Buhari kede pe ko gba iṣẹ lọwọ Babatunde Fowler ti saa rẹ pari lana ọjọ Aiku gẹgẹ bii alaga FIRS.

Kete ti awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ba ti fọwọsi yiyan Muhammed naa lo maa bẹrẹ iṣẹ ni FIRS lẹkunrẹrẹ.

Awọn ọmọ igbimọ tuntun naajẹ ti ẹlẹnu pupọ.

Ẹni kọọkan lati ẹya mẹfa agbegbe ti a pin orilẹ-ede Naijiria si, ati aṣoju lati awọn ileeṣe ijọba kọọkan.

Garba Shehu ni ijọba gba pe Babatunde Fowler yoo fi eto gbogbo silẹ fun adari ti ipo rẹ ga julọ lasiko yii ninu ajọ FIRS.

Wo àwọn ǹkan tó ṣẹlẹ̀ lásìkò tí Fowler ń tukọ̀ FIRS láti 2015

FIRS Babatunde Fowler to jẹ ọ̀rẹ́ Ọṣinbajo nì àwọn èèyàn n bèèrè bóyá Buhari á tún yàn sípò ṣugbọn Ohun to n tan ni ọdun eegun, bo pẹ bo ya ọmọ alagbaa n pada bọ wa tọrọ akara jẹ ẹkọ ni ọrọ naa jasi.

Fowler gbà pé òdiwọ̀n owó ti òun pa wọle si apo ijọba lolori aṣeyọri oun àti pé ìpènija ni ki àwọn eeyan mọ ìdí tí wọn fi gbọdọ san owo ori.

Ọpọ sọrọ lori idagbasoke to ba nomba iye owo to wọle si asunwọn ijọba lasiko ti Fowler wa nibẹ.

Fowler ni ajọ FIRS to n gba owo ori wọle fun ijọba apapọ Naijiria pọ sii lasiko oun.

Fowler ni owo ti oun pa wọle lọdun 2018 lo pọju ni asunwọn ijọba ninu itan Naijiria, iyẹn lasiko to pa 5.3 tiriliọnu naira wọle.

Bakan naa lo ni sisan owo ori lona igbalode nipa lilo ayelujara wa lara aṣeyọri Fowler nigba to jẹ adari FIRS.

Bakan naa ni Fowler ba awọn ile iṣẹ nlanla kan pòó lori ọrọ owo ori to yẹ ki wọn maa san.

Awọn miran mẹnuba eyi to ṣe pẹlu ileeṣẹ bii ti MTN ti wọn kọkọ kọ̀ lati san owo ori tuntun ti wọn bu fun wọn pe o pọju.

Fowler funra rẹ ṣalaye ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe ihuwasi awọn eniyan lori sisan owó orí jẹ ipenija nla fun ajọ naa lasiko oun.

Koko ipenija ti awọn eeyan n pariwo lasiko Fowler ni pe o jẹ ki owo ori pọ sii.

Ọpọ gba pe igbagbọ rẹ pe ki ijọba moju kuro ninu epo rọbi lati owo na wa di ajaga sọrun awọn ara ilu ati ileeṣẹ.

Awọn miran ni o dabi pe FIRS n da ṣiṣẹ laisi ifọwọsopọ awọn ileeṣe ijọba miran bii ki wọn ma mọ ni pato iye ti awọn kan n san.

Iṣẹlẹ lori ọrọ IGR ati odiwọn iye owo to wọle ati eyi to jade naa tun kun ara ẹfọri to la kọja

Babatunde Fowler ati igbakeji aarẹ Osinbajo jẹ lọ sile iwe ni lọdun diẹ sẹyin ko to gba ipo alaga ajọ FIRS.

Loni ọjọ Aje, ọjọ kẹsan an, oṣu kejila, ọdun 2019 ni Fowler fi fipo silẹ lẹyin ti iyansipo rẹ pari lanaa, ọjọ Aiku.

Ọpọ eeyan lo ṣi n woye boya aarẹ Buhari maa tun Fowler yan fun saa keji.

Ọdún 2015 ni Babatunde Fowler di alaga àjọ to n risi ọrọ owó orí ni Naijiria FIRS, ṣe aarẹ Buhari fẹ lòó lẹẹkan sii ni ibeere bayii.

Babatunde Fowler to jẹ ọ̀rẹ́ Ọṣinbajo nì àwọn èèyàn n bèèrè bóyá Buhari á tún yàn sípò

Logunjọ, oṣu kẹjọ, ọdun 2015 ni ijọba Buhari ti yan Babatunde Fowler sipo adari ajọ FIRS to n risi ọrọ owo ori ni Naijiria.

Ọjọ kẹsan an, oṣu kejila, ọdun 2015 ni ile igbimọ aṣojuṣofin fọwọ si yiyan Fowler sipo.

Lọjọ Aiku yii ni saa ọdun mẹrin ti ijọba yan Fowler sipo pari ni eyi ti ileeṣẹ aarẹ Buhari ko tii sọ nkanakn nipa iyansipo rẹ lẹẹkan sii tabi ko yan ẹlomii.

Igbesẹ wo ló rọ̀ mọ́ yíyan adarí FIRS ní Nàìjíríà?

Ajọ FIRS labẹ ofin Naijiria ni awọn gbendeke to rọ mọ yiyan ẹnikẹni lati tukọ ajọ FIRS ni Naijiria.

Ofin to da ajọ FIRS silẹ faaye gba pe ki aarẹ to ba n tukọ Naijiria yan ẹni to wuu sipo naa.

Aarẹ gbọdọ fi orukọ ẹni naa ranṣẹ sile igbimọ aṣofin ki wọn le buwọlu iyansipo iru ẹni bẹẹ.

Ọdun mẹrin ni saa kọọkan fun ẹnikẹni ti a ba yan sipo alaga naa.

Ẹẹmeji pere to jẹ ọdun mẹjọ lapapọ ni ẹnikẹni le di ipo alaga ajọ FIRS mu.

Tọkunrin tobinrin lo le di ipo naa mu ti ile igbimọ ba ti fọwọ si iyansipo naa.

O ṣeeṣe ko jẹ pe Adari eto gbogbo ti wọn fun ni ipo Coordinating Director nile iṣẹ FIRS ni o maa dipo mu bi Fowler ṣe ti pari saa rẹ yii ti aarẹ Buhari ko si kede tabi forukọ Fowler ranṣẹ fun sa keji.