You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
NHIS: Lẹyin ọpọlọpọ àbájáde ìwádìí, Buhari ni ki ọjọgbọn Yusuf máa lọ
Ọjọgbọn Mohammed Sambo di alaga ajọ NHIS tuntun.
Oun ni wọn yan dipo Ọjọgbọn Usman Yusuf ti aarẹ Mohammadu Buhari yọ kuro nipo naa nitori iwa ajẹbanu.
Ajọ to n mojuto ọrọ adojutofo ninu eto ilera awọn eniyan Naijiria ni àwọn ẹsun pupọ jade nibẹ nipa ṣiṣe owo ilu mọkumọku.
Bakan naa ni aarẹ Buhari ti gba pé ki wọn tu ile awọn ọmọ igbimọ adari ajọ adojutofo NHIS ka.
Arabinrin Boade Akinola to jẹ oludari eto ifitonileti fun ileeṣẹ ijọba apapọ to n mojuto eto ilera ni Abuja lo fidi ọrọ yii mulẹ.
O ni lẹyin abajade gbogbo iwadii ti awọn igbimọ ti Buhari yan lati ṣe iwadii ẹsun ikowojẹ naa ni Aarẹ gbe igbesẹ yii.
Ninu oṣu kejila, ọdun 2018 ni awọn igbimọ oluwadii yii ti gba aarẹ Buhari nimọran pe ko da ọjọgbọn Yusuf duro lẹnu iṣẹ rẹ.
Aarẹ Buhari ni ki ọjọgbọn Sambo maa ba iṣẹ lọ titi ti wọn yoo fi yan igbimọ miran fun ajọ adojutofo ilera NHIS.
Ọdun 2016 ni ọjọgbọn Yusuf bẹrẹ iṣẹ adari ajọ NHIS.
Ninu ọrọ tirẹ lo ti fi ẹsun kan awọn ileeṣẹ to n ṣakoso lilọ ile iwosan awọn eeyan (HMO) pe awọn ni wọn n ṣe owo awọn eniyan niṣekuṣe.