You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ruga Settlement: Ìpínlẹ̀ Oyo àti Eko kò ní èròǹgbà láti kópa nínú ètò Ruga Settlement
Ninu ọrọ ti wọn ba BBC Yoruba sọ, awọn akọwe agba fun ọrọ to kan araalu fun gomina ipinlẹ Ọyọ ati Eko, Taiwo Adisa ati Gboyega Akọsile sọ pe ijọba ipinlẹ awọn ko nifẹ si eto Ruga Settlement ti ijọba apapọ n gbeero rẹ.
Ninu ọrọ tiẹ, Taiwo Adisa sọ pe ipinlẹ Ọyọ ko ni i kopa ninu eto naa, nitori pe ipinlẹ naa ko nilo eto naa.
O ni eto ijọba apapọ ni, ko si si lara nkan ti awọn eniyan ipinlẹ Ọyọ n fẹ.
Fun akẹẹgbẹ rẹ nipinlẹ Eko, Gboyega akọsile sọ pe ipinlẹ Eko ko tii ni erongba kankan lati darapọ mọ eto naa.
Lalẹ ọjọ Aiku nijọba apapọ Naijiria fidi rẹ mulẹ pe ipinlẹ to ba wu lo le darapọ mọ eto Ruga settlement.
Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari lori eto iroyin ati ipolongo, Garba Shehu ṣalaye pe ipinlẹ mejila lo ti fi erongba ọkan wọn lati darapọ mọ eto naa to ba bẹrẹ. Ṣugbọn ko darukọ awọn ipinlẹ naa.
Lati bi ọjọ melo kan ti ijọba apapọ ti kede pe oun yoo da awọn agbegbe igberiko silẹ fun awọn agbẹ nkan ọsin, ni ẹnu ti n kun un, ti ọpọ eniyan, paapa lati awọn ipinlẹ to wa ni ẹkùn Gusu Naijiria si n sọ wi pe ọna lati sọ orilẹede Naijiria di ti ẹya Fulani nikan ni Aarẹ Buhari n wa pẹlu eto naa.
Ọpọ ti lẹ n kesi awọn gomina ipinlẹ wọn lati ma gba eto naa laaye ni ipinlẹ wọn.
Lori ẹsun yii, ileeṣẹ aarẹ ti sọ pe ko si ipinnu tabi erongba kankan lati fi ipa gba ilẹ lọwọ ẹnikẹni, to si fẹsun kan pe awọn kan lara awọn ipinlẹ ti ko nifẹ si eto naa lo n ṣi awọn araalu lọna.
Ileeṣẹ aarẹ sọ pe ''ọna lati fi opin si ija ati wahala to n waye ni gbogbo igba laarin awọn daran-daran ati agbẹ ni.''