Anthony Joshua vs Andy Ruiz: DJ Cuppy ní ìgbà gbogbo ni ọlọ́kàn bí Joshua maa ń borí

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Oni lonii jẹ, ẹni a bẹ lọwẹ. Lalẹ oni ni abẹṣẹ ku bi ojo ọmọ bibi orilẹede Naijiria to n ṣoju ilẹ Gẹeṣi yoo maa ta kaungbọn pẹlu alatako rẹ, Andy Ruiz Jr niluu Riyadh lorilẹede Saudi Arabia.

Awọn mejeeji ti n leri leka lati ọjọ yii wa, koda awọn alatilẹyin wọn naa ko gbẹyin nipa lileri ṣaaju ọjọ oni.

Ọkan lara awọn ololufẹ AJ ni olorin takasufe, ọmọ Naijiria, DJ Cuppy.

Cuppy sọrọ loju opo Instagram rẹ, ẹrẹ pe ni gbogbo igba ni lawọn ọkan mimọ maa n bori, iyẹn ni pe Joshua lọka mimọ.

Niluu Riyadh ti ija naa yoo ti waye nilẹ Larubawa ni Cuppy ti fọrọ yii lede loju opo Instagram rẹ.

Mo ṣetán láti kojú Andy Ruiz ni Saudi lọ́jọ́ Sátidé- Anthony Joshua

Ọjọ nii pẹ, ipade kii jina. Ọla ọjọ keje oṣu kejila ọdun 2019 ni atunja ija laarin Anthony Joshua ati Andy Ruiz Jr yoo waye lorilẹede Saudi Arabia.

Ṣaaju ija ọhun, gbajugbaja, abẹṣẹ ku bi ojo, Joshua ti sọ pe oun ti gbaradi fun ija ọjọ Abamẹta.

Joshua tun ni ilumọọka abẹṣẹ ku bi ojo to ti fẹyin ti, Wladimir Klitschko tiẹ gba oun ni imọran pe k'oun ma ṣe lo ẹrọ ibanisọrọ rara ti ija naa yoo fi waye.

Ẹ o ranti pe Ruiz Jr ya agbado ha si ọpọlọpọ lẹnu nigba to lu Joshua bi ẹni n lu bara nigba ti wọn kọkọ koju ara wọn niluu New York, lorilẹede Amẹrika.

Nigba naa ni Joshua padanu bẹniti rẹ mẹtẹẹta to ko kalẹ nibi ija naa.

Amọ Joshua to gba ami ẹyẹ wura fun ilẹ Gẹẹsi ninu idije Olympics lọdun 2012 ti n ṣe igbaradi pẹlu awọn abẹṣẹ ku bi ojo miiran ṣaaju ija rẹ pẹlu Ruiz Jr.

Koda Joshua sọ pe oun ko ni dunnu ti oun ba jawe olubori ninu ija ọjọ Abamẹta.

Mike Tyson ti oun naa ti fẹyin ti kilọ pe afaimọ ki ẹru ijakulẹ ninu ija akọkọ maa mu Joshua padanu lẹẹkan si ni Saudi.

Bi Joshua ti n leri leka naa ni Ruiz Jr ko dakẹ, O ni digbi loun n duro de Joshua ninu ija ọjọ Satide.