Anthony Joshua vs Andy Ruiz Jr: AJ lóun ṣetán láti kojú Ruiz nínú ìjà ọjọ́ Sátidé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọjọ nii pẹ, ipade kii jina. Ọla ọjọ keje oṣu kejila ọdun 2019 ni atunja ija laarin Anthony Joshua ati Andy Ruiz Jr yoo waye lorilẹede Saudi Arabia.

Ṣaaju ija ọhun, gbajugbaja, abẹṣẹ ku bi ojo, Joshua ti sọ pe oun ti gbaradi fun ija ọjọ Abamẹta.

Joshua tun ni ilumọọka abẹṣẹ ku bi ojo to ti fẹyin ti, Wladimir Klitschko tiẹ gba oun ni imọran pe k'oun ma ṣe lo ẹrọ ibanisọrọ rara ti ija naa yoo fi waye.

Ẹ o ranti pe Ruiz Jr ya agbado ha si ọpọlọpọ lẹnu nigba to lu Joshua bi ẹni n lu bara nigba ti wọn kọkọ koju ara wọn niluu New York, lorilẹede Amẹrika.

Nigba naa ni Joshua padanu bẹniti rẹ mẹtẹẹta to ko kalẹ nibi ija naa.

Amọ Joshua to gba ami ẹyẹ wura fun ilẹ Gẹẹsi ninu idije Olympics lọdun 2012 ti n ṣe igbaradi pẹlu awọn abẹṣẹ ku bi ojo miiran ṣaaju ija rẹ pẹlu Ruiz Jr.

Koda Joshua sọ pe oun ko ni dunnu ti oun ba jawe olubori ninu ija ọjọ Abamẹta.

Mike Tyson ti oun naa ti fẹyin ti kilọ pe afaimọ ki ẹru ijakulẹ ninu ija akọkọ maa mu Joshua padanu lẹẹkan si ni Saudi.

Bi Joshua ti n leri leka naa ni Ruiz Jr ko dakẹ, O ni digbi loun n duro de Joshua ninu ija ọjọ Satide.