You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Reinhard Bonnke: Ajíhìnrere àgbáyé Reinhard Bonnke papòdà lẹ́ni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Iku doro, iku ṣeka, iku ti mu gbajugba ajiyinrere agbaye, Reinhard Bonnke lọ lẹni ọdun mọkandinlọgọrin.
Ninu atẹjade kan ti iyawo rẹ, Annie Bonnke buwọ lu loju opo Facebook rẹ ni wọn ti kede iku ojiṣẹ Ọlọrun yii.
Wọn sọ ninu atẹjade naa pe pẹlu alaafia ni Ọgbẹni Bonnke fi pada lọ ba Ẹlẹdaa rẹ ni ọrun.
Fun ọgọta ọdun sẹyin, Bonnke ṣiṣẹ ajihinrere kaakiri agbaye papaa julọ nilẹ Afirika, o ṣe eto isọji kaakiri awọn orilẹ-ede.
Idile rẹ ki gbogbo eeyan fun iranwọ ati igbaruku ti wọn fun Bonnke eleyi to jẹ ko ṣe aṣeyọri ninu iṣẹ ipe rẹ.