Uber and Bolt airport ban: Àjọ FAAN sọ pé òun kò fi òfin dé wọ́n

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Àjọ to n mojuto awọn papakọ ofurufu ni Naijiria, FAAN, ti kede pe irọ ni iroyin to sọ pe oun ti fi ofin de awọn oni takisi igbalode Uber ati Bolt lati ma a gbe ero ni awọn papakọ ofurufu.

Olori ẹka ibanisọrọ nileeṣẹ ajọ FAAN, Henrietta Yakubu, sọ fun BBC pe kii ṣe lati ọdọ ajọ naa ni ikede to n lọ lori ayelujara ti wa.

Yakubu sọ eyi lẹyin ti iroyin ti tàn kaakiri pẹlu aworan kan to ṣafihan rẹ pe ajọ naa ti fi ofin de awọn takisi igbalode ọhun.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, Arabinrin Yakubu sọ wi pe, awọn onitakisi to ti wa tẹlẹ ni papakọ ofurufu ni ẹru n ba pe ki awọn takisi igbalode naa ma gba iṣẹ lọwọ wọn.

Eyi lo si mu ki wọn o gbe patako ikede kan sita ni papakọ ofurufu ilu Calabar, nipinlẹ Cross River, pe ẹgbẹrun mẹwaa Naira ni onitakisi Uber tabi Bolt to ba gbe eero ni papakọ ofurufu naa yoo san, lai jẹ ki ajọ naa o mọ si i.

"Awọn eniyan ni ẹtọ lati lo takisi to ba wu wọn lai si ibẹru."

Bakan naa ni ajọ FAAN sọ lori ayelujara pe oun ti gbe patako ikede naa kuro.

Amọ ṣa, ko to o di pe ajọ FAAN sọ eero rẹ lori ọrọ naa ni awọn ọmọ Naijiria kan ti n sọrọ tako 'igbesẹ aja naa'.

Ninu ọrọ ti ẹ naa, Ọga ni ẹka ibanisọrọ ileeṣẹ Uber West Africa, Efosa Aiyevbomwan sọ fun BBC pe "Uber yoo tẹsiwaju lati maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn to ba yẹ lasiko.

O ni Uber a ri i daju pe awọn ko ru ofin kankan, ati lati ṣi ilẹkun anfaani fun awọn to ni ọkọ, awọn awakọ, to fi mọ awọn to n wọ awọn takisi naa."