You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Fídíò ìbálòpọ̀ ''Sex Tape''tó lu síta mú kí àwọn ọ̀dọ́ dá ṣèríà fáwọn olólùfẹ́ méjì níwájú aàfin Kábíyèsí
Awọn ọmọ orile-ede Ghana ti n sọ tẹnu wọn lẹyin tawọn ọdọ kan ni aafin ọba Waa Naa da sẹria fun arakunrin ati arabinrin kan ti fọnran fidio ibalopọ ''sex tape'' ti wọn ya papọ̀ lu sita.
Fọnran fidio bi wọn ṣe da sẹria fun awọn mejeeji yi naa lu sita bi i ti ibalopọ ti awọn naa ya.
Ninu fidio ṣẹria taa n wi yi,wọn so arakunrin yi ati obinrin yi mọ ara opo kan ninu aafin ọba ni Upper West Region. Idi tawọn to da sẹria yi lawọn fi ṣe bẹẹ ni pe ko tọ bawọn mejeeji ṣe ya aworan ibalopọ wọn.
Amọ iwa tawọn ọdọ to lu wọn yi hu ko dunmọ awọn eeyan Ghana ninu to fi mọ Naa Fuseini Seidu Pelpuo IV, ,olori igbimọ awọn lọbalọba to ṣapejuwe iwa yi ''gẹgẹ bi iwa ẹranko''
Agbẹnusọ fun olori awọn lọbalọba naa, Jinpehi Naa, sọ fun ileeṣẹ iroyin Ghana News Agency pe awọn lọbalọba bẹnu atẹ lu lilu ti wọn lu awọn mejeeji yi.
“A n fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọlọpaa lati ri bi wọn yoo ṣe yẹ ọrọ yi bo bo ṣe yẹ. Kii ṣe nkan taa faramọ ni iwa ti wọ́n hu yi.Awa ko faramọ rara''
Gẹgẹ bi igbimọ lọbalọba yi ṣe sọ, ohun to yẹ ki awọn ọdọ yi ṣe ni pe ki wọn fa ọrọ naa le awọn ọlọpaa lọwọ dipo ki wọn fiya jẹ wọn lọwọ ara wọn.
Ghana Sex video: Bi ọrọ naa ṣe wọ wa ti wón fi da ṣeria fawọn ololufẹ ni aafin Kabiyesi
Bi ere bi ere ni fọnran fidio ibalopọ arakunriun ati arabinrin yi bẹrẹ si ni gbode loju opo ayelujara.
Ami idanimọ ọjọ ti wọn gbe fidio naa sita fi han pe ni ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Karun ọdun 2022 la ri lara rẹ.
Iroyin sọ pe bawọn ọdọ ti inu wọn ko dun si fidio yi ṣe ri ni wọn ba bẹrẹ wa wọn kan ti wọn si wọ wọn lọ si ile kabiyesi Waa Naa lagbegbe wọn ṣugbọn wọn ko ba oriade nile.
Igba naa ni wọn ba pinnu ti wọn si so wọn mọ igi da sẹria ẹgba fun awọn mejeeji.
Awọn ẹgbẹ ajafẹtọmọniyan to fi mọ awọn ọmọ ilẹ Ghana to gbarata mii ti kesi awọn alaṣẹ lati wa awọn to wa nidi iwa yi ki wọn si fimu wọn jofin.
Ileeṣẹ ọlọpaa lawọn yoo fi fidio yi wa awọn to wa nidi iwa yi
Ẹwẹ awọn ọlọpaa ti fi iwe pe awọn eeyan kan to wa ni aafin kabiyesi ti iṣẹlẹ naa ti waye botilẹjẹ wi pe Kabiyesi naa ko si nile nigba ti wọn gbe igbesẹ ṣẹria yi.