Ebele Obiano and Bianca Ojukwu: Kí ni orísun ìkùnsínú tó wà láàrin wọn saájú ìjà lásìkò ayẹyẹ ìbúra?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọjọru ni fidio kan jade sori ayelujara, eyi to ṣafihan bi iyawo gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Anambra, Ebele Obiano ṣe dide ni ori ijoko rẹ, to si lọ ọ ba Bianca Ojukwu .

Nibi ayẹyẹ ibura wọle fun gomina tuntun fun ipinlẹ naa, Charles Soludo, ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Bo tilẹ jẹ pe nkan ti Ebele sọ fun Bianca ko jẹ mimọ, ki idarudapọ to waye laarin wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọ iroyin si gba ori ayelujara pe Bianca fọ eti Ebele.

Koda, ọrọ naa si n fa ariyanjiyan lọwọ lori ayelujara.

Ṣugbọn ni Ọjọbọ, Bianca sọ fun ileeṣẹ iroyin Ariise News pe eebu ati awọn ọrọ buruku ni Ebele wa sọ si oun nibi ti oun joko si.

O ni o beere lọwọ oun pe "ki lo wa a sẹ nibi, ṣe bi o ni o ko nii darapọ mọ ohunkohun ti ẹgbẹ APGA ba n ṣe mọ."

O ṣalaye pe oun ko fun ni esi kankan, nitori pe awọn to joko ti oun ni ki oun dakẹ. O ni bi Ebele ṣe n sọrọ, lo n fi ọwọ gun oun ni ejika.

"Mo sọ fun pe ko ma fọwọ kan mi ni ejika mọ, ṣugbọn ko dahun. Niogba to ya, o gbiyanju lati fa gele ori mi jabọ, nitori naa ni mo sẹ fun ni igbati."

Kini orisun ija wọn yii gan-an?

Ṣaaju ayẹyẹ ibura wọle fun Soludo, ikunsinu ti wa laarin Bianca Ojukwu ati awọn olori ẹgbẹ osẹlu APGA kan, paapaa Willie Obiano to ṣẹṣẹ fi ipo gomina silẹ ni ipinlẹ Anambra.

Oloṣelu kan ti a ko daraukọ rẹ sọ pe laarin ọdun 2018 si 2019 ni ikunsinu naa ti bẹrẹ.

Asiko yii ni Bianca Ojukwu fẹẹ dije fun ipo sẹnetọ ni Anambra South, ṣugbọn iyawo gomina, Ebele Obiano fi orukọ ẹlomiran, Prince Nicholas Ukachukwu, silẹ fun ipo naa.

Nicholas Ukachukwu si ni ẹgbẹ APGA fun ni tikẹẹti lati dije fun ipo sẹnetọ to wu Bianca.

"Lati igba naa ni ikunsinu ti bẹrẹ laarin Ebele ati Bianca, debi pe wọn kii sọ nkan to dara nipa ara wọn."

Koda, Bianca han ninu fidio kan lọdun 2018 nibi to ti n bu ẹnu atẹ lu awọn adari ẹgbẹ APGA, to si ṣapejuwe wọn gẹgẹ bi ọdalẹ.

Ọkan gboogi si ni Willie Obiano to jẹ gomina nigba naa lara awọn olori ẹgbẹ.

Kilo kọkọ ṣẹlẹ ni ọjọ ti ija igboro naa waye?

Ni owurọ ọjọ kẹtadinlogun, osu Kẹta, ọdun 2022, ti Obiano fẹ ẹ gbe ijọba silẹ, Bianca kọ awọn ọrọ kan si oju opo ayelujara Facebook rẹ pe inu oun dun pe ẹlomiran di gomina.

O ni asiko ominira ati irapada ti de fun Anambra, ati pe ọjọ naa fihan pe ko si ẹni to le wa ni ipo agbara titi lai.

A ko wa a le sọ boya awọn nkan to kọ ni iyawo Willie Obiano, Ebele ri, to fi lọ koju Bianca nibi ayẹyẹ naa.