El-Zakzaky: Buhari ló ní kí wọn pa mi, inú rẹ̀ kò sì dùn títí tó fi gbọ́ pé wọn ti sun ilé mi

Asaaju ijọ Shiite, Sheik Ibrahim El-Zakzaky ti fi ẹsun kan ileesẹ ologun Naijiria pe wọn da ibọn bo oun atawọn alatilẹyin oun.

Bakan naa lo tun ni wọn kan nipa fun iyawo oun lati bọ awọn asọ to wa lara rẹ silẹ lọdun 2015 ti wọn ya bo ile oun nilu Zaria.

O fi ọrọ yii lede ninu ifọrọwanilẹnuwo akọkọ iru rẹ ti yoo se pẹlu ileesẹ iroyin BBC lati igba ti wọn ti tu silẹ ni ahamọ.

O ni bi wọn si se da ibọn bolẹ ni yara kekere toun wa kun fun ọta ibọn ati eefin.

Diẹ ree ninu ifọrọwanilẹnuwo ti El Zakzaky se pẹlu ileesẹ BBC, eyi ti olori ẹka BBC Hausa, Aliyu Abdullahi Tanko se fun.

Ọmọ bibi inu mi mẹrin ati ọpọ ọmọ ti mo gba tọ, ni ologun pa:

"Lasiko naa, ọmọ mi kekere meji lo wa lọwọ ọtun mi, ti iyawo mi si wa niwaju mi, tawọn ọmọ yoku wa lọwọ osi.

Ni kukuru, wọn yinbọn mọ ọkan lara awọn ọmọkunrin mi lori, tii se ọmọ ọdun mẹẹdogun."

El-zakzaky ni ọmọ mẹrin ni ologun pa ninu awọn ọmọ oun, ọkunrin mẹta ati obinrin kan ni afikun awọn ọmọ miran ti oun gba tọ, ti wọn pa wọn papọ.

Bakan naa lo fikun pe ọta ibọn awọn ologun ti ba itan oun jẹ, ti oun si n gba itọju nile iwosan awọn ologun fun osu mẹta gbako.

Ologun ti fi ọta ba itan mi jẹ:

O ni inu oun dun pe wọn se isẹ abẹ lori itan oun apa ọtun. nibi ti ọta ibọn ti baa, bakana naa lo ni ọta ibọn tun ba oun ni apa ọtun pẹlu.

Sheikh Zakzaky salaye pe wọn dabọn bo ilẹ ni, ti eeyan mẹrin si ya wọ inu iyara kolobo toun wa.

O ni oun foju ri awọn eeyan naa to wa ka oun mọle, ti wọn si wa niwaju ati lẹyin oun, ti wọn n da ibọn bolẹ.

Nigba to n sẹ lori iroyin kan to ni o kọ lati jẹ ki wọn gbe oun lọ, Sheikh Zakzaky ni rara, wọn kan de, ti wọn si bẹrẹ si sina ibọn bolẹ ni.

"Wọn lawọn fẹ yọ awọn nnkan kuro ninu ile mi, ti mo si yari fun wọn. Aimọye eeyan ni wọn pa, ki wọn to de ọdọ wa.

Wọn dana sun ile mi, ti wọn si ni awa la dana sunle naa:

Nigba to n sọrọ lori ile rẹ to jona, agba ẹsin naa ni awọn ologun to wa lo dana sun ile oun, ti wọn si ni awọn funra awọn lo dana sun ile ara wọn.

Sheikh Zakzaky ni lootọ ni ẹru ba oun lọjọ ti wọn wa naa.

O ni eeyan kan beere pe se oun fẹ sa kuro nibẹ, ti oun si ni Ọlọrun ko ni jẹ nitori ko si bi oun se le jẹ ki wọn pa awọn eeyan, ki oun si sa lọ nibẹ.

"Tori naa, mo ni mo maa duro de wọn lati seku pa mi.

Asẹ ti wọn pa ni wọn n tẹle. Aarẹ fun ara rẹ lo ni ki wọn wa pa mi lati Kaduna. Inu rẹ ko dun titi ti wọn fi sọ fun pe wọn ti dana sun ile mi.

Ẹsun lasan kọ ni eleyi. Nkan ti aarẹ sọ ree pe se emi ni mo ro pe mo n da ijọba se?

Ki leyi tunmọ si? Wọn ni El Zakzaky fẹ doju ijọba bolẹ ni."

Ki ni El-Zakzaky yoo ba aarẹ Buhari sọ ti wọn ba foju kanra lọjọ kan?

Nigba ti BBC beere lọwọ El-Zakzaky pe to ba foju kan aarẹ Buhari ati Gomina El Rufai, ki ni nkan to maa sọ fun wọn?

Agba ijọ ẹlẹsin naa fesi pada pe "Mo maa sọ fun wọn pe ki wọn pari isẹ ti wọn bẹrẹ. Ki wọn gba laada isẹ wọn."

Sheikh Zakzaky wa fi ireti han pe pẹlu ogo Olorun, lọjọ kan, ireti wa pe oun yoo fi oju kan ilu Zaria pada, tí ko si ni si ohunkohun ti yoo da oun duro.

Sugbọn o ni nnkan to se pataki bayi ni ki alaafi pada si agọ ara oun.

O ni gbogbo nnkan to ba sọnu tẹlẹ ni yoo pada, gbogbo dukia ti oun si padanu ni Zaria lawọn yoo ri gba pada.

Ki lo sẹlẹ si Sheik El-Zakzaky sẹyin?

Sheik Ibrahim El-Zakzaky ni oludasilẹ ati adari ijọ ẹlẹsin Islam kan ti wọn n pe Shiite.

Ẹgbẹlẹgbẹ ọmọlẹyin lo n tọ lẹyin, ti okiki rẹ si kan jale jako kọja orilẹede Naijiria lọ soke okun.

Amọ ti kọja ọdun mẹfa bayii ti ikọlu laarin awọn ọmọlẹyin rẹ ati awọn ọmọ ogun Naijiria waye, eyi to mu ọpọ ẹmi lọ.

Ikọlu yii ko si sẹyin bi wọn se sọ pe awọn alatilẹyin rẹ dina oju ọna tawọn ọmọogun fẹ gba kọja nigba ti wọn n lọ si ilu Zaria.

Ọpọ igba ni awọn ikọ El Zakzaky ti sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ yii, to si ni ijọba fi ọrọ naa kẹwọ ni, ki wọn baa le se ikọlu si awọn ni 2015.

Ajọ ajafẹtọmọniyan nii, Amnesty International, si ti sọ pe eeyan ojilelọọdunrun ati marun, 345 lo ti ba ikọlu ologun si awọn ọmọlẹyin El Zazaky lọ.

Ni osu Keje ọdun 2021 nileẹjọ giga kan ni Kaduna tu El-Zakzaky ati iyawo rẹ silẹ pe wọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, lẹyin ti wọn lo ọdun mẹfaa ni atimọle.