Shiite: Ìjọba Kaduna ní òun yóò pe ẹjọ́ láti tako El-Zakzaky tó fẹ́ gba ìtọ́jú ní India

Ijọba ipinlẹ Kaduna ti kede pe oun ko faramọ asẹ ti ileẹjọ pa pe ki wọn fun olori ijọ Shiite, Ibrahim El Zakzaky ati iyawo rẹ ni aaye lati lọ gba itọju loke okun.

Amọ o fikun pe ti asẹ naa yoo ba mulẹ, awọn gbedeke kan wa ti oun yoo gbe kalẹ, eyi ti olori ijọ Shiite naa ati iyawo rẹ ti wọn dijọ n jẹjọ lọwọ, gbọdọ tẹle ki ọna to si silẹ fun wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu atẹjade kan ti ijọba ipinlẹ Kaduna fisita lati ipasẹ Kọmisana rẹ fun eto iroyin, Samuel Aruwan ni eyi ti jẹyọ pẹlu afikun pe ijọba ipinlẹ Kaduna yoo pe ẹjọ tako asẹ ileeẹjọ naa, eyi to fun El Zakzaky ati iyawo rẹ laaye lati lọ gba itọju loke okun.

Ijọba Kaduna ni bi o tilẹ jẹ pe oun maa n bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan lati wa itọju fun ara rẹ ni ibikibi lagbaye amọ nibamu pẹlu aṣẹ ileẹjọ naa, awọn igbesẹ kan gbọdọ wa ti olori ẹsin naa gbọdọ tẹle, ki oun to lọ.

Ilana ti ijọba Kaduna fi lelẹ ki El-Zakzaky tó lọ gba itọju:

  • Ileesẹ to wa fun ọrọ ilẹ okeere tijọba apapọ ilẹ wa, gbọdọ lọ fidi rẹ mulẹ ni ile iwosan ti El Zakzaky ati iyawo rẹ fẹ lọ nilẹ India, pe lootọ ni ile iwosan naa n reti wọn fun itọju
  • El Zakzaky ati iyawo rẹ ni ikọọkan wọn gbọdọ fi ọwọ siwe pe awọn yoo pada wa si orilẹede Naijiria lati tẹsiwaju pẹlu ẹjọ ti wọn n jẹ lọwọ nile ẹjọ ni kete ti wọn ba ti gba itọju tan ni India
  • El Zakzaky ati iyawo rẹ ni yoo san gbogbo owo ti wọn yoo fi rin irinajo lọ si India, owo itọju ara wọn nile iwosan ati awọn owo ti wọn yoo na lasiko ti wọn ba lọ gba itọju naa
  • Ikọọkan awọn olujẹjọ naa yoo fa oniduro meji-meji silẹ, ọkan ninu aọn oniduro naa yoo jẹ oloye abi Emir onipo kinni, n igba ti oniduro keji yoo jẹ eekan ilu kan ti yoo tọwọ bọ iwe pe oun yoo fa olujẹjọ ti oun duro fun kalẹ nigba kuugba ti ile ẹjọ ba fẹ rii. Bakan naa ni irufẹ awọn oniduro bẹẹ gbọdọ fi ẹri silẹ pe wọn ni ilẹ ni aarin ilu Kaduna
  • Ijọba ilẹ Naijiria gbọdọ gba iwe idaniloju lati ọdọ ijọba orilẹede India pe oun ko ni gba awọn olujẹjọ naa laaye lati se atipo ni orilẹede wọn, tabi ki ẹnikẹni beere lorukọ wọn lati se atipo ni ilẹ India, yatọ si pe wọn lọ se itọju ara wọn nibẹ
  • Ikọọkan awọn olujẹjọ ọhun lo gbọdọ kọ iwe adehun, ti agbẹjọro wọn yoo si fọwọsi pe, lasiko tawọn ba lọ gba itọju ni India, awọn ko ni se ohunkohun to lee pagidina igbẹjọ to n lọ lọwọ, tabi alaafia ati eto aabo orilẹede Naijiria ati ofin ilẹ India lọna kọna
  • Ileesẹ asoju ijọba ilẹ wa to wa ni India yoo kọkọ se ayẹwo, ti yoo si fọwọsi pe alejo kankan to ni anfaani lati ri awọn olujẹjọ mejeeji lasiko ti wọn ba wa ni orilẹede India.