You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Femi Falana: Ojú Elzakzaky kan ti fọ́ nítorí àìsí ìtójú tó
Ile ẹjọ giga ni Kaduna ti pasẹ ki ijọba ipinlẹ Kaduna fun adari ẹgbẹ Shia lorilẹ-ede Naijiria, Ibrahim Elzakzaky ati iyawo rẹ, Zinat ni eto iwosan to peye.
Adajọ Gideon Kurada pasẹ naa lasiko ti wọn gbo ẹsun onigun mẹjọ ti ijọba ipinlẹ Kaduna fi kan awọn mejeeji pe wọn n daabo bo awọn ọdaran ati awọn apaniyan to n gbogun ti ipinlẹ naa.
Agbẹjọro fun Elzakzaky, Femi Falana sọ fun ile ẹjọ pe lati ọjọ kẹrinla, oṣu kejila, ọdun 2015 ti wọn ti wa latimọle ni wọn ko ti ni itọju to peye.
Ninu ọrọ rẹ, Falana ni airi itọju to peye lasiko ni Elzakzaky se padanu oju rẹ kan, ati wi pe ọta ibọn si wa lara iyawo rẹ.
Adajọ Kurada wa sun igbẹjọ naa si Ọjọ Karundinlọgbọn, Osu Kẹta ,ọdun 2019.