Shiite: Ojú Zakzaky kan ti fọ́, májèlé sì wà nínú ara rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ kò sì le è rìn mọ́

Awọn ọmọ ẹgbẹ Shiitee sọ pe idajọ ileẹjọ giga ipinlẹ Kaduna lọjọ Aje jẹ idajọ ododo to lodi si iwa ika ati iwa tani yoo mu mi.

Ileẹjọ fun Ibrahim El-Zakzaky ati iyawo rẹ ni beeli lati lọ tọju ara wọn lorilẹede India, bo tilẹ jẹ pe ileẹjọ naa paṣẹ pe kawọn to n ṣeto igbẹjọ tẹ wọn lọ.

Alaga igbimọ awọn ọmọ ẹgbẹ Shiite ti wọn ti n ṣewọde, eyi ti wọn fi n sọ fun ijọba lati fun olori wọn ati iyawọ rẹ lominira, Abdurrahman Abububakar Yola ni, ẹgbẹ Shiite nigbagbọ ninu titẹle ofin ati lilepa alaafia lati yanju aawọ lai lo ipa bo tilẹ jẹ pe ijọba mọọmọ bi awọn ninu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹ o ranti pe El-Zakzaky ati iyawo rẹ beere fun beeli nitori wọn ṣaisan latimọle ti wọn wa nitori ijiya tawọn ologun fi jẹ awọn mejeeji.

Ẹgbẹ Shiite tun sọ ninu atẹjade ti wọn fi sita pe, bi wọn ti fi El-Zakzaky ati iyawo rẹ mọle nile iṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lodi si ẹtọ ọmọniyan.

Wọn tun fẹsun kan ile iṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ pe wọn fun un awọn mejeeji ni mọjele jẹ latimọle, ti oju olori awọn kan si ti fọ nigba ti iyawo rẹ ko lee da rin funra rẹ mọ lai lo kẹkẹ ti wọn fi n tii kiri.

Ẹgbẹ naa ni gbogbo ijiya yii latimọle ti jẹ ki El-Zakzaky ati iyawo rẹ ni aarun rọpa-rọsẹ lọpọ igba, eyi si n jẹ ki ẹru maa bawọn pe aarun yii tun le pada ṣe wọn.

Wọn ni oju El-Zakzaky kan fọ nitori ijiya tawọn ologunh fi jẹẹ, ati pe ekeji naa tun le fọ ti ko ba ri itọju gidi lasiko.

Ẹgbẹ Shiite tun sọ pe ninu irora ti ko ṣe fẹnu sọ ni iyawo El-Zakzaky wa nitori ọta ibọn tawọn ologun yin mọ si mwa lara rẹ.

Wọn ni nitori ailera awọn mejeeji ni wọn ko fi le lọ si ileẹjọ fun igbẹjọ lati gba beeli fun wọn lẹẹmeji ọtọtọ bayii.

Ẹgbẹ Shiite tun sọ siwaju si ninu atẹjade ti wọn fi sita pe awọn ile iwosan ni Naijiria ko le ṣetọju El-Zakzaky ati iyawo rẹ ninu oniruuru aarun lo ṣe wọn latimọle ti wa lati ọjọ yii.

Wọn ni afaimọ kọwọ maa bọ sori ti ileẹjọ ko ba fun wọn ni beeli lọjọ Aje.

Ẹgbẹ Shiite ni ijọba Naijiria ko bọwọ fun ofin orilẹede naa, eleyi to mu ijọba ma tẹle aṣẹ ileẹjọ wi pe ki wọn fun El-Zakzaky ati iyawo lominira.

Wọn lo atẹjade naa lati ki awọn ajafẹtọ ọmọmiyan, awọn akọroyin, ati gbogbo eeyan to gbaruku ti ẹgbẹ Shiite nigba ti wọn n ṣe iwọde lati beere idajọ otitọ fun El-Zakzaky ati iyawo rẹ atawọn ti awọn ologun pa niluu Zaria.

Ọpọ ẹmi lo ti sun tawọn miiran si farapa ninu ikọlu to waye laarin awọn ọlọpaa ati ẹgbẹ Shiite.

Iléẹjọ́ gba onídùròó El-Zakzaky, ó ní kó lọ gba ìtọ́jú lókè òkun

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní sọ pé ileẹjọ giga ilu Kaduna, ti gba oniduro olori ẹsin Shiite, Ibrahim El-Zakzaky ati iyawo rẹ.

Zakzaky ati iyawo rẹ lo ti wa ni ahamọ lati bii ọdun marun sẹyin, ti ileẹjọ ko si gba oniduro rẹ.

Bakan naa ni ile ẹjọ naa ni El Zakzaky ati aya rẹ ni anfaani bayii lati rin irin ajo lọ gba itọju ni orilẹede India, amọ awọn asoju ikọ olupẹjọ gbọdọ kọwọrin pẹlu rẹ lọ si ibi ti yoo ti gba itọju naa.

Bẹẹ ba gbagbe, awọn ọmọ ẹgbẹ Shiitee lo ti gun le iwọde alagbara eyi to la ẹmi lọ lati bii ọjọ melo kan, ti wọn si n beere fun itusilẹ asaaju wọn to wa ni ahamọ naa.

Lati idaji oni ọjọ Aje, ni awọn agbofinro ti duro wa wa wa si ẹnu ọna abawọle ile ẹjọ naa, ti wọn si n se ayẹwo awn eeyan to fẹ wọle sibẹ.