Yoruba: Báwo lo ṣe gbọ́ èdè rẹ sí?

Awọn akanlo ede tabi ọrọ Yoruba kan wa ti itumọ wọn fara sin to si jẹ wi pe gẹgẹ bi awọn agba ṣe sọ ọ, ọlọgbọn lo n tu u, ọmanran lo n mọ ọ.

Gẹgẹ bi mimọ ede Yoruba ṣe ti wa n lọ sokun igbagbe paapaa laarin awọn ọdọ ode oni, awọn ọrọ to jẹ wi pe itumọ wọn ko to nkankan ti wa di ohun to n kọ awọn ọmọ Yoruba leyin.

Eyi lo mu igbiyanju BBC Yoruba waye lati maa ṣe ohun to lee mu gbigbe ede ati aṣa Yoruba larugẹ waye.

"À-rí-gi-ṣẹ́-gi" lọ̀rọ̀ ti a mu lonii, awọn itumọ to wọle kuku wa ṣugbọn ọpọ ọdọ Yoruba ṣi nilo akọmọlede.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ si