Jimọh Ọladiran: Ọwọ́ tẹ́ afurasí méjì tí wọn ló tan bàbá jáde kúrò nílé láti pa á

Awọn amookunṣeka kan tun ti ran bàbá àgbàlagbà, ẹni ọdún marundinlaadọrun, Alagba Jimọh Ọladiran, lọ s'ọrun aremabọ nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Ọjọ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kejìlá osù kẹta la gbọ pé wọn tán Jimọh,to n siṣẹ kafinta ni Ọbantoko, lọ sí inú igbó kan to wa nijọba ibilẹ Abẹokuta North, ipinlẹ naa.

A gbọ pé igi ni wọn fọ mọ baba naa lori, titi to fi jáde laye, ti wọn sì lọ ju oku rẹ seti odò, ìyẹn ni Abule kan ti wọn pe ni Aṣipa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bawo ni isẹlẹ naa se waye, ki ni baba Oladiran se fun wn, irọ wo ni wọn pa fun, ki wọn to tan jade ninu ile ati bi asiri ọna naa se tu.

Ọmọ oloogbe naa to ke gbajare tọ BBC Yoruba sọrọ ilẹ kun, to si n fika hanu pe oro nla ni awọn afurasi naa da ẹbi oun.

Bawo ni baba ẹni ọdun marundinlaadọsan se poora:

Sulaiman Ọladiran to jẹ akọbi oloogbe, nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, ni abule Aṣipa ni baba àwọn dagbere pe òun ń lọ ni ago mẹwàá aarọ.

O tẹsiwaju pé saara ni baba oun sọ pé òun pẹlu aburo rẹ fẹẹ lọ ṣe, ṣugbọn ti ko pada sile latigba naa.

O ṣàlàyé pé " Baba mi ati aburo rẹ lo fẹ lọ ṣe saara níbẹ. Igba to di irọlẹ, mi o ri wọn.

Mo wa pe ẹgbọn wa to jẹ Baálẹ̀ ilu Aṣipa yìí, Oloye Kehinde Omirinde, to si sọ pe ka ṣi ni sùúrù di ọjọ keji, ka tó mọ igbesẹ ti a máa gbé lati wa wọn lọ.

Nigba ti a ko ri wọn di agogo mejila ọjọ keji, mo tun pé Baálẹ̀ yìí, wọn wà sọ pé a kò tún gbọdọ duro mọ.

A jọ lọ si ibi ti baba dagbere pe oun n lọ, ta si pade Ibrahim Mufatiu toun pẹlu baba wa jọ lọ.

Oun lo sọ pé ka ni sùúrù, nitori pe abule keji ni baba wa lọ, ati pé wọn máa tóo de.

O loun n bọ lati lọ wo baba wa, tó sì gba ọna isalẹ ti odò wa.

Awọn to wa níbẹ ti a jọ n sọrọ lọwọ, a ti ṣakiyesi pe ọkan wọn kò balẹ, wọn ti n gbọn. Ibẹ ni ara ti n fu mi."

Sulaiman salaye siwaju si pe Mufutau pada de lootọ, to si ni ki wọn se oun jẹjẹ amọ bi wọn tun se n beere baba lọwọ rẹ, lo ba salọ mọ wọn lọwọ.

Wọn fi ada ati ohun ija oloro sare le wa, awọn ọlọpaa OPMESA lo gba wa silẹ:

Akọbi baba ti wọn n wa naa ni awọn eeyan to ku ninu ile naa ko ada ati nnkan ìjà oloro, ti wọn fi n le wa.

Ibi ti awọn ti n salọ, ni awọn ọlọpaa OPMESA lagbegbe abule Ọpẹji, ti daabo bo awọn.

Eyi si lo mu ki awọn ọmọ baba naa fi isẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si tọpasẹ Mufutau, ti ọwọ wọn si ba a.

A gbọ pe lọjọ keji, tii se ọjọ Aje ti ọwọ ọlọpaa tẹ Mufatiu, lo wa mu awọn ọlọpaa lọ sí etí odò tí wọn pa baba naa si.

Akoba nla ni wọn fẹ fi iku baba Jimoh se fun mi - Baalẹ Ashipa

Baálẹ̀ Aṣipa, Oloye Mọshood Kẹhinde Omirinde, nigba toun naa n ba BBC Yoruba sọrọ, ni oun ko mọ àwọn èèyàn to pa baba naa rí.

O salaye pe àkóbá nla ni wọn fẹ fi iku rẹ ṣe fún oun.

"Mi o mọ ibi ti wọn ti ri ẹrọ ibanisọrọ mi, ti wọn fi pe mi pe awọn fẹ da oko, mọ sọ pé kò saaye.

Ibrahim Mufatiu ati baba ẹ, Aafa Mufatiu ni wọn pe mi.

Ọjọ kẹta lẹyin ẹ ni wọn lọ pe ẹgbọn mi, Alagba Jimọh Ọladiran wa lati Ọbantoko.

"Ẹgbọn mi yii ni wọn sọ pé kí n jẹ ki wọn da oko naa. Mo jẹ ko ye wọn pe awọn ẹbi gbọdọ mọ si ki n to gba wọn láàyè.

Igba to tun ya ni wọn sọ pé awọn fẹ ṣe saara, ati pe awọn yóò pe mi bi akoko ba to.

"Aburo baba mi ni baba ti wọn pa yii, ṣugbọn mi o mọ bi wọn ṣe tán mọ awọn to pa wọn yìí.

Wọn sọ pe idile iya lọ pa awọn pọ, ṣugbọn mi o le dahun ẹ. Lọjọ ti wọn pe mi pe awọn fẹ lọ ṣe saara yìí, ọkan mi ko lọ, idi ree ti mi o fi tẹle wọn lọ.

"Ka ni aburo baba mi pe mi pe awọn fẹ tẹle wọn lọ ní, máa sọ pé wọn kò gbọdọ lọ, ṣugbọn wọn kò pé mi.

Igba ti mo máa gbọ ni awọn aburo mi bẹrẹ síi pé mi pe awọn ko rí baba wọn. Kí n ma fa ọrọ gun, oku baba la pada rí o. O ṣi n jẹ iyalẹnu fún mi."

Ki ni ileesẹ ọlọpaa se si isẹlẹ yii:

Lọwọ lọwọ bayii, ọwọ ileesẹ ọlọpaa ti tẹ awọn afurasi to seku pa oloogbe naa, ti wọn si ti n sọ ohun ti wọn mọ nipa iku baba Jimoh Oladiran.