Farmers-Herdsmen Clashes in Oyo: Àwọn afurasí Fulani mú ọ̀kan lára ọwọ́ fijilańté tí wọn gé lọ

Àwọn afurasi Fulani ti se ìkọlù sì arákùnrin Fijilante kan tí orúkọ rẹ jẹ Amodu Bakare ni agbegbe iwere ilé ni Ijoba Ibile Iwajowa ni Ipinle Oyo.

Lasiko ikọlu naa, ni wọn sì gé ọwọ rẹ méjèèjì, eyi to mu ko wa ninu inira nla.

Arákùnrin náà ni ó yàn isẹ ẹsọ alaabo ìgbèríko layo gege bí ìṣẹ ojo rẹ kì ó tó di pé àwọn afurasi Fulani naa ṣe ni ijamba.

Osisẹ alaabo naa si wa nile iwosan nibi to ti n gba itọju, ti ilera rẹ si wa nipo to lagbara.

Awọn mọlẹbi Bakare ti wa fi isẹlẹ naa to ile sofin ipinlẹ Oyo leti, ki wọn le gbe igbesẹ to yẹ nipa rẹ.

Afurasi Fulani mu ọkan lara ọwọ fijilante ti wọn ge lọ:

Asofin to soju ibile Iwajowa nile asofin ipinle Oyo, Hon Akeem Adedibu ba BBC Yoruba lori isẹlẹ naa.

Adedibu ní agbègbè Abuja lèda ni isele naa ti waye, nibi ti àwọn afurasi Fulani kan ti dá Bakare dúró tì wọn sì gé ọwọ rẹ méjèèjì.

Asofin Adedibu salaye pe awọn afurasi Fulani naa ati osisẹ alaabo ọhun ni wọn pade ara wọn ni alẹ, ni ẹsẹ ko gbeji nibiti ti ko si ẹni kankan.

O fikun pe awọn mejeeji kọju ija sira wọn, ti awọn afurasi Fulani yii si gba ọkunrin naa mu, ge ni ọwọ mejeeji.

O tesiwaju pé àwọn afurasi naa mú ọ̀kan lára ọwọ ọkunrin náà lọ lẹyin ti wọn ge lọwọ mejeeji tan.

"Alẹ ìjọ Friday ni wọn pé mi pé nnkàn bayi sẹlẹ, tí mo sì ti rán àwọn ọmọ ìlú lọ láti ṣe abewo sì arákùnrin náa.

Ìyàlẹ́nu lọ je fún mi leyin gbogbo akitiyan ijoba lati dekun ìwà burúkú yii, a sì rí àwọn korolosi eda kan tí wọn ṣe ijamba sì àwọn eyan wa."

"Wọn gé ọwọ méjèèjì, wọn tún wà mú ìkan lọ pélu wọn. Arakunrin naa wa ilé ìwòsàn bayi níbi tí ó ti je ìrora."

Ile asofin ti pe fun iwadi awọn agbofinro lori isẹlẹ yii:

Asofin Akeem Adedibu, nínú igbinyanju rẹ gbé oro naa lọ si iwájú igbimo asofin kesan tí ipinle Oyo ti adari ilé, asofin Debo Ogundoyin n dari.

"Ọ̀rọ̀ naa ti wá ní iwájú ilé igbimo asofin ipinle Oyo, tí adari ilési ti pé fún iwadi lowo awon agbófinró lori isẹlẹ naa."

Bakan naa lo ni ki àwọn Fulani àti àwọn igbimọ asofin ṣe ìpàdé lórí bí wọn yoo ṣe dekun ìwà búburú naa ni awujọ wá.