Housemaid allegedly kills Mistress‘s Baby: Ọmọ ọ̀dọ̀ jẹ́wọ́ pé ẹgbẹ́ àjẹ́ tí òun wà ló ní kí òun mú ẹ̀jẹ̀ ọmọ ọ̀gá òun wá

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ ọmọ ọdọ kan, ọmọ ọdun mẹẹdogun , Chiamaka Odo, ti wọn lo pa ọmọ ọga rẹ to jẹ ọmọ oṣu mẹwaa, nipinlẹ Eko.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ naa, Adekunle Ajisebutu, sọ fun awọn akọroyin pe, afurasi naa jẹwọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti oun n ṣe, lo ni ki oun mú ẹ̀jẹ̀ ọmọ naa wa sinu ẹgbẹ́ .

O ni ẹgbẹ okunkun Ogoloma ni oun wa nipinlẹ Anambra.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni afurasi ọhun tun se alaye fun awọn agbofinro lori bo se wọ inu ẹgbẹ ajẹ naa lati kekere.

Bisikiiti ni awọn ọrẹ mi nile ẹkọ alakọbẹrẹ fi tan mi wọnu ẹgbẹ ajẹ:

Gẹgẹ bi afurasi naa ṣe sọ fun awọn akọroyin to gba ọrọ lẹnu rẹ, o ni awọn ọrẹ oun nile ẹkọ alakọbẹrẹ lo mu oun wọ ẹgbẹ nipasẹ bisikiiti ti wọn fun oun jẹ.

"Lẹyin ti mo jẹ bisikiiti naa tan , mo ba ara mi ni ibi kan loru. Wọn ki mi kaabọ.

"Nigba ti mo n bọ nipinlẹ Eko, wọn sọ fun mi pe ki n mu ẹ̀jẹ̀ wa, ṣugbọn mo sọ fun wọn pe mi o fẹ ẹ ta ẹjẹ eeyan silẹ."

Odo ṣalaye pe wọn gba oun nimọran lati ba inu ẹnikan jẹ, niwọn igba to jẹ pe iṣẹ ọmọ titọ ni oun fẹ ẹ lọ sẹ ni Eko.

Lẹyin asiko diẹ to ti wa ni Eko, wọn sọ fun ni alẹ ọjọ Satide, ọjọ karun-un, oṣu Kẹta, pe awọn yoo fun ni ọrun pa, to ba fi kuna lati mu ọmọ naa fun wọn".

Mo pe orukọ ọmọ ọga mi, ẹjẹ rẹ si kun inu abọ:

Afurasi naa tẹsiwaju, to si jẹwọ nipa awọn igbesẹ to gbe lati gba ẹmi ọmọ ọga rẹ.

"Ninu ipade ni oru ọjọ naa loju ala mi, wọn gbe abọ kan fun mi pe ki n pe orukọ ọmọde naa si ni igba mẹrin.

"Bi mo ṣe pe e ni ẹjẹ kun inu abọ naa, ti ọmọ ọga mi si ku loju aye."

O ni oun ma n ba ara oun ninu ẹgbẹ Ogoloma, ti oun ba ti sun.

Iroyin bi awọn ọmọ ọdọ tabi abani tọju ọmọ ṣe n pa awọn ọga tabi ibatan ọga wọn wọpọ ni Naijiria.

Yatọ si eyi, awọn ọmọ ọdọ miran ma n ji ọmọ ọga wọn gbe fun tita, tabi lati gba owo.