Mide Martins: Gbajúgbajà òṣèré ṣàlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí lóko sinimá

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Kò sí iṣẹ́ tàbí òwò tí ènìyàn bá ń ṣe tí kò ní àwọn ewu tirẹ̀.

Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Mide Martins Abiodun ti tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ ọ̀rọ̀ lórí ohun tí ojú rẹ̀ rí láìpẹ́ yìí nígbà tí ó ń ṣe sinimá rẹ̀ kan, Onitemi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde.

Mide Martins ṣàlàyé pé lásìkò tí òun ń ya abala eré náà lọ́wọ́ ni ẹsẹ̀ òun yẹ̀ gẹ̀rẹ̀, tí òun ṣubú, tí òun sì forí gbá táńgaran àlẹ̀mọ́lé ìyẹn táìsì (tiles).

Ó ní òun fi orí gbá taisi naa gidigidi àti pé Ọlọ́run ló yọ òun tí òun kò fi pàdánù ọpọlọ lórí ìjàmbá náà tó wáyé.

Bákan náà ló fi kun pé Ọlọ́run ló kó òun yọ, tí òun fóríbọ́ lọ́wọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò bá di ibá míì fún òun.

Nígbà tó fi fọ́nrán kan nínú eré náà léde lórí ẹ̀rọ Instagram rẹ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ fún àtìlẹyìn tí wọ́n ṣe fún òun lórí sinimá náà.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn laarin awọn osere tiata?

Ní bí ọjọ́ mélòó sẹ́yìn ni Mide Martins fi fọ́nrán kan léde níbi tó ti ń sunkún nítorí pé ilé iṣẹ tó bá dòwòpọ̀ kọ̀ láti fi àwọn ibì kan nínú sinimá rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde sí inú fíìmù náà.

Nínú fọ́nrán náà ló ti ṣàlàyé gbogbo àwọn ohun tó là kọjá láti ri dájú pé iṣẹ́ náà kẹ́sẹ járí.

Ìyá Rainbow bú sígbé nígbà tó ń ṣeré lọ́wọ́

Kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyìí tí àwọn òṣèré tíátà máa ń la ewu kọjá tàbí tí wọn yóò rí ìrírí tí yóò pa wọ́n lẹ́kún nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ òòjọ́ wọn.

Yoruba ni ọrọ arokan nii fa ẹkun asunundakẹ wa nitori ẹkun lo n ba ikun wa, ọrọ lo si n ba moko moro wa.

Nigba miran, ti ẹda ba si ro arokan, omije ni yoo maa ja bọ ni oju rẹ, o si le jẹ omije ayọ abi ti idakeji rẹ.

Amọ ti ẹni to n ro arokan yii ba wa jẹ agbalagba, ti onitọ̀ọun si sadede maa wa ẹkun mu lairotẹlẹ, o ni ohun to ri.

Bi ọrọ se jẹ ree pẹlu gbajumọ osere tiata kan, mama Idowu Phillips, ti ọpọ eeyan mọ si Mama Rainbow.

Ọpọ osere tiata lo la ẹnu silẹ, lai le pa de mọ nigba ti Mama Rainbow bẹrẹ ẹkun alagbara yii.

Oko ere tiata ni wọn wa, nibi ti wọn ti n ya sinima kan, ti wọn si fun iya agbalagba naa ni ojuse kan lati se.

Mama Rainbow, ti yoo pe ẹni ọgọrin ọdun lọdun yii, ni wọn fun ni ojuse lati sun ẹkun ninu ere naa ni apa kan sinima ọhun.

Amọ ọrọ naa kuro ni ere tabi awada nigba ti Mama Rainbow ko dakẹ ẹsun sisun, to si fi iriri igbe aye rẹ wọ inu ere to n se.

Ojuse ti wọn fun naa lo se ni laanu pupọ, arokan ti Mama ro nipa ere naa, ati ọpọ ohun to sẹlẹ nile aye, ti oju rẹ ti ri si lo fa ẹkun asun un dakẹ naa wa.

Ta ni Mide Martins?

Gbajúgbajà òṣèré tíátà Yorùbá ní Mide Martins.

Ó jẹ́ ọmọ bíbí gbajúgbajà òṣèré Funmi Martins tó di olóògbé lọdún 2002.

Lẹ́yìn tí ìyá rẹ̀ papòdà ní Mide bẹ̀rẹ̀ eré tíátà láti ri pé orípa ìyá rẹ̀ kò parẹ́.

Ní ọjọ́ kejìlá ọdún 1979 ni wọ́n bí Mide Martins.

Ó fẹ́ adarí eré, Afeez Abiodun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Afeez ọwọ́ tí Ọlọ́run sì fi ọmọ ta wọ́n lọ́rẹ.