You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iya Rainbow: Kí ló ń pa Mama Rainbow ní ẹ̀kún àsun-ùn-dákẹ́
Yoruba ni ọrọ arokan nii fa ẹkun asunundakẹ wa nitori ẹkun lo n ba ikun wa, ọrọ lo si n ba moko moro wa.
Nigba miran, ti ẹda ba si ro arokan, omije ni yoo maa ja bọ ni oju rẹ, o si le jẹ omije ayọ abi ti idakeji rẹ.
Amọ ti ẹni to n ro arokan yii ba wa jẹ agbalagba, ti onitọ̀ọun si sadede maa wa ẹkun mu lairotẹlẹ, o ni ohun to ri.
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
- Iya Rainbow di ònílé tuntun, ilé méjì ni wọ́n fi ta á lọ́rẹ
- Iya Rainbow jẹ́ gbajúmọ̀, àmọ́ kí lo mọ̀ nípa rẹ̀?
- Princess tún sọ òkò ọ̀rọ̀ sí Iya Rainbow lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Àwa kìí jà lásìkò tiwa, ta ló bí ẹ tí wàa máa jà? - Iya Rainbow
- Ọjọ́ mẹ́rin ni mo fi bẹ Princess pé kí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha má di ẹjọ́ - Iya Rainbow
- Kíni ẹ mọ̀ nípa Mama Rainbow tó jẹ́ àgbà òṣẹ̀ré tíátà Yoruba?
- Gbajue ń lọ orúkọ mi láti gba owó- Mama Rainbow
Bi ọrọ se jẹ ree pẹlu gbajumọ osere tiata kan, mama Idowu Phillips, ti ọpọ eeyan mọ si Mama Rainbow.
Ki lo mu Mama Rainbow maa sun ẹkun fun igba pipẹ?
Ọpọ osere tiata lo la ẹnu silẹ, lai le pa de mọ nigba ti Mama Rainbow bẹrẹ ẹkun alagbara yii.
Oko ere tiata ni wọn wa, nibi ti wọn ti n ya sinima kan, ti wọn si fun iya agbalagba naa ni ojuse kan lati se.
Mama Rainbow, ti yoo pe ẹni ọgọrin ọdun lọdun yii, ni wọn fun ni ojuse lati sun ẹkun ninu ere naa ni apa kan sinima ọhun.
Amọ ọrọ naa kuro ni ere tabi awada nigba ti Mama Rainbow ko dakẹ ẹsun sisun, to si fi iriri igbe aye rẹ wọ inu ere to n se.
Ojuse ti wọn fun naa lo se ni laanu pupọ, arokan ti Mama ro nipa ere naa, ati ọpọ ohun to sẹlẹ nile aye, ti oju rẹ ti ri si lo fa ẹkun asun un dakẹ naa wa.
Ina ọmọ ko ni jo wa o - Muyiwa Ademola
Agba osere tiata kan, Muyiwa Ademola lo ke gbajare isẹlẹ to waye pẹlu Mama Rainbow naa loju opo Instagram rẹ.
Ademola, ti ọpọ eeyan mọ Muyi Authentic, lo n fi tdun tẹdun sọrọ pe isẹ ni awọn n se lọwọ ni oko ere, ti Mama Rainbow si wa nibẹ.
O ni Mama naa bu sẹkun lasiko kan ninu sinima naa, ti awọn si rẹ mama yii ni ẹkun fun igba pipẹ, amọ ti ko dakẹ.
O ni isẹlẹ to n waye pẹlu Mama Rainbow yii lo n se afihan bi awọn se maa gbe ara awọn wọ inu ere sise.
Ademola ni asiko tawọn ba ti ronu kọja lọ si aye miran lati se ojuse awọn daadaa ninu ere yii, lo maa n nira lati pe ara awọn pada wale.
O wa pari ọrọ rẹ nipa sisọ fun Mama Rainbow pe "Ina ọmọ ko ni jo wa o, Ọjọ yin yoo tubọ dalẹ.
Ta ni Mama Rainbow:
Ọjọ Kẹrindinlogun osu Kẹ́wa ọdun 1942, eyiun ọgọrin ọdun sẹyin ni Mama Rainbow de ile aye.
Ọmọbibi ilu Ijebu Ode nipinlẹ Ogun nii se, to si wa lara awọn agba ọjẹ obinrin to bẹrẹ isẹ tiata ni aye Hebert Ogunde.
Mama Rainbow ti kopa ninu ọpọlọpọ ere tiata ati sinima, to si ti gba ami ẹyẹ ri gẹgẹ bi akọni osere ni Naijiria.