King burnt in Ogun State: Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ afurasí 11 tó dáná sun ọba nílú Agodo

Ko din ni afurasi mọkanla, ti ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ lori iku Oba Ayinde Odetola, Olu ilu Agodo, ti wọn dana sun lasiko diẹ sẹyin.

Iṣẹlẹ yi waye ni ilu Agodo lẹba Papalanto ni ijọba ibilẹ Ewekoro ni ipinlẹ Ogun.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kinni, ọdun 2022, ni awọn janduku deede yabo Oba Odetola, lasiko to ṣe abẹwo si iboji aburo rẹ lati tun ayika ibẹ ṣe.

Awọn janduku naa fi iya jẹ Kabiesi ati awọn mọlẹbi rẹ to a pẹlu rẹ, ki wọn o to gbe oun funra rẹ lọ pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ.

Iroyin sọ è inu igbo kan nitosi ibi ikọlu naa ni wọn wa kabiesi lọ, wọn ti i mọ inu ọkọ, wọn si dana sun mọ ibẹ.

Iṣẹlẹ naa fa ibẹru-bojo ni ilu naa, eyi to mu ki awọn araalu kan sa fi ilu silẹ.

Ṣugbọn lọjọ Aje ni ẹkun keji ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, kede pe oun ti mu afurasi mọkanla mu lori ipaniyan ọhun.

Agbẹnusọ fun ẹka naa, Hauwa Idris-Adamu sọ pe ẹnikan ninu ẹbi Oba Odetola, lo fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti pe ẹnikan to n jẹ Gbeminiyi Sotade, ti ọpọ eeyan mọ si Okon, ati awọn isọmọgbe rẹ lo pa kabiesi.

Onitọhun ṣọ fun awọn ọlọpaa pe Sotade lo lewaju awọn janduku bi aadọta wa sori ilẹ ti kabiesi ti lọ wo iboji aburo rẹ.

Yatọ si pe wọn pa Oba Odetola, mọlẹbi rẹ mẹta ni wọn tun fi àdá ṣá yan-na-yan-na.

Idris-Adamu sọ pe awọn afurasi mọkanla ti ọwọ tẹ, ti jẹwọ pe awọn lọwọ ninu ipaniyan naa.

O ṣalaye pe wọn jẹwọ pe kabiesi naa ma n gba ilẹ onilẹ, ni awọn ṣe pa a .

Bakan naa lo sọ pe awọn ṣi n gbiyanju lati mu awọn afurasi yooku.

Ó ṣojú mi nígbà tí wọn dáná sun ọba, bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé rèé - Ẹlẹ́rìí

O ṣoju mi koro kan ti ṣalaye fun BBC bi awọn afurasi janduku kan ṣe ṣeku pa Ayinde Odetola, Oba ilu Agodo ni ijọba ibilẹ Ewekoro ni Ogun.

Arakunrin naa sọ pe oun, oriade naa ati awọn eeyan mii n ṣiṣẹ lori ilẹ ẹgbọn ọba lọwọ ni lasiko tawọn janduku naa ṣe ikọlu si wọn.

''A n ro oko lori ilẹ ẹgbọn Kabiyesi ti awọn kan pa laipẹ yi ni .Baa ṣe n ṣiṣẹ lọ, ọkan lara awọn janduku yi paṣẹ kawọn iyoku doju ija kọ wa''

"Bi mo ṣe n ba Kabiyesi sọrọ, awọn janduku naa kan fọ pako mọ mi ni. Wọn fi pako yii lu mi titi ti mo fi farapa.

Bi awọn eeyan ṣe n rin yika Kabiyesi lati daabo bo wọn, ọkan ninu awọn janduku yii ba da bẹntiroo si wọn lori .''

Kabiyesi du ẹmi rẹ amọ ẹpa ko boro:

O tẹ siwaju pe ''Kabiyesi ja witiwiti lọ si idi ọkọ wọn nitori oju ti n ta wọn. Inu ọkọ yii ni wọn fọ pako mọ wọn lori ti wọn si daku sibẹ''

Arakunrin yii sọ pe lẹyin ti wọn lu Kabiyesi laludaku, wọn kọju si oun naa, ti wọn si n lu oun lalu sare.

"Wọn le mi wọ igbo ti mo si gba ibẹ jade si Oke Iganmu nibi tawọn ọlọpaa wa. Nigba ti mo de ibẹ, mo sọ fawọn ọlọpaa pe ki wọn jọwọ tẹle mi pada lati lọ doola Kabiyesi ṣugbọn awọn ọlọpaa lawọn ko ni le tẹle mi''

O ṣoju mi koro naa sọ pe oun ko si nibẹ nigba ti wọn dana sun ọkọ Kabiyesi