EFCC Arrests Willie Obiano: Gómìnà àná ní Anambra àná dèrò àtìmọ́lè EFCC lọ́jọ́ kan náà tó gbé ìjọba sílẹ̀

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC, ti fi ṣikun ofin mu gomina ipinlẹ Anambra ana, Willie Obiano.

Wọn mu gomina tẹlẹ naa lọjọ kan naa to gbe ijọba fun ẹni to gba ipo lọwọ rẹ, Ọjọgbọn Charles Soludo.

Agbẹnusọ EFCC, Wilson Uwajaren ṣalaye fun akọroyin BBC pe Obiano ti wa ni ọọfisi awọn to wa niluu Eko bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n sọrọ lori idi ti wọn ṣe fi panpẹ ofin mu, Uwujaren sọ pe ilẹ ti ta si ti awọn ti n ṣọ loju-lẹsẹ, amọ ọwọ awọn ti tẹ bayii ti ko si labẹ abo gẹgẹ bii gomina mọ.

O ni "O ti pẹ ti a ti n ṣọ, ti a ba dẹ ti n ṣọ eeyan o tumọ si pe a n wa irufẹ ẹni beẹ ni."

"Ṣaaju akoko yii, a ko le fi ọwọ kan nitori o wa labẹ abo gẹgẹ bii gomina, amọ ni bayii to ti fi ipo naa silẹ ko si labẹ abo gomina mọ."

Uwujaren pari ọrọ rẹ pe ọwọ tẹ awọn gomina ana ọhun lasiko to n mura lati fi Naijiria silẹ.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Ọ̀rọ̀ di eré ìtàgé, aya gómìnà àná l'Anambra tahùn sí Bianca Ojukwu níbi ayẹyẹ ìbúra fún gómìnà tuntun

Lónìí ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹta ọdún 2022 ni wọ́n búra wọlé fún Ọ̀jọ̀gbọ́n Charles Soludo gẹ́gẹ́ bí gómìnà ẹlẹ́ẹ̀kẹfà ìpínlẹ̀ Anambra láti ìgbà tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti padà sí ìjọba alágbádá.

Ṣùgbọ́n lòdì sí ètò ìbúrawọlé tó máa ń wáyé pẹ̀lú ayẹyẹ ńlá, ètò ìbúrawọlé náà kò pẹ́ rárá.

Gómìnà àná tó ń kúrò lórí oyè, Willy Obiano tí ṣaájú kéde pé gbọ̀ngán ayẹyẹ International Conference Centre tó gbá ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ènìyàn ni ìbúrawọlé yóò ti wáyé.

Àmọ́ gómìnà tuntun náà, Soludo ní òun kò fẹ́ ariwo àti èrò púpọ̀ níbi ayẹyẹ náà.

Kọ́míṣọ́nà fétò ìròyìn ìpínlẹ̀ Anambra, Don Adinuba ti ṣaájú kéde pé ètò náà kò ní ju ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lọ.

Adinuba ní àwọn kò ní ju àádọ́ta ènìyàn tí yóò wà níbi aẹyẹ náà àti pé gbogbo àwọn Ọba àti àwọn eléré ìdárayá kò ní sí níbẹ̀.

Ifanfa wáyé níbi ìbúrawọlé fún gómìnà Soludo:

Se ni ọrọ di ifanfa níbi ayẹyẹ ìbúrawọlé fun gómìnà Soludo nígbà tí ìyàwó gómìnà tó ń kógbá sílé, Ebelechukwu Obiano àti Bianca Ojukwu tahùn síra.

Bianca Ojukwu ni aya oloogbe Odumekwu Ojukwu to lewaju ogun abẹle to waye ni Naijiria laarin ọdun 1967 si 1970.

Bakan naa tun ni baba Bianca, Oloye C.C Onoh ti jẹ gomina tẹlẹ nipinlẹ Anambra.

Fidio bi aawọ naa se waye si ti gba ori ayelujara kan.

Amọ ohun ta mọ ni pe ní kété tí wọ́n búra wọlé fún Soludo ni Ebelechukwu lọ bá Bianca níbi tí ó jòkòó sí, tí ariwo sì sọ láti ibẹ̀.

Amọ BBC Yorùbá kò lè fi ìdí ohun tó ṣokùnfà ifanfa naa mulẹ ti Ebele àti Bianca fí tahùn síra.

Sùgbọ́n ìròyìn fìdí rẹ̀ múlẹ pé Willy Obiano àti ìyàwó rẹ̀ fi gbọ̀ngán ayẹyẹ náà sílẹ̀ ní kété tí wọ́n búra fún Soludo tán.