Charly Boy: ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ni kò ní ipa rere míì nínú àjọsepọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin ju ìbálòpọ̀ lọ

Gbajúgbajà olórin àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, Charles Oputa ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Charly Boy ti rọ àwọn obìnrin láti ri pé kìí ṣe ìbálòpọ̀ nìkan ni ipa tí wọ́n le kó nínú eré ìfẹ́.

Charly Boy sọ èyí lórí ẹ̀rọ ayélujára Instagram rẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì.

Ó ní àwọn obìnrin gbọ́dọ̀ lè máa ran ọkùnrin lọ́wọ́ yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ nìkan, kì wọ́n sì máa wá nǹkan ṣe, kí wọ́n yé dúró de ọkùnrin tó lówó lọ́wọ́ láti fẹ́.

Kini Charly Boy tun se?

Charly Boy fikun pe kò tọ́ kí obìnrin tí kò ní iṣẹ́ lọ́wọ́ máa wá ọkùnrin tó ti tó tán láti fẹ́ láì ní ní ipa kankan tí yóò máa kó nínú eré ìfẹ́ wọn.

Ó ní "ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin máa ń sọ̀ pé àwọn ọkùnrin ń já àwọn kulẹ̀ nítorí ìbálòpọ̀.

Púpọ̀ nínú àwọn obìnrin ló ti sọ ara wọn di ohun ìbálòpọ̀ lásán látàrí à ti má jẹ̀ ẹ́ kí ọkùnrin jáwọn kulẹ̀, ó le má jẹ̀ ẹ́ pé kìí ṣe ìbálòpọ̀ ló ń fàá.

"Tí a bá yọ ìbálopọ̀ kúrò nínú eré ìfẹ́, ẹ ó ri wí pé ọ̀pọ̀ obìnrin ni kò ní ipa kankan nínú àjọṣepọ̀ wọn."

Agba Oje onkorin naa ni pe: "Yàtọ̀ sí ìbálòpọ̀, kíni o ní láti fi ran ọkùnrin lọ́wọ́, ṣé owó ni, àdúrà ni tàbí ọgbọ́n orí?"

"Ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín máa ń bèèrè fún kò ju báàgì, bàtà, fóònù, aṣọ àti ìjáde lọ."

"Ǹjẹ́ ẹ jọ dámọ̀ràn lórí bí ọjọ́ iwájú yín yóò ṣe rí."

Charly Boy wá rọ àwọn obìnrrin láti jẹ́ obìnrin tí ọkùnrin kò ní fẹ́ pàdánù láéláé.