You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
NURTW suspends MC Oluomo: MC Oluomo yapá kúró ní NURTW, Ó ní kí Sanwo-Olu gba ìṣàkóso ìdíkọ̀ èrò l'Eko
MC Oluọmọ kọ ìwé rańse si oluillese egbẹ́ awako
Lẹyin wakati diẹ ti igbimọ adari apapọ ẹgbẹ awakọ ero lorilẹ-ede Naijiria paṣẹ idaduro fun Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluọmọ, pe ko fi ipo alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Eko silẹ, MC Oluọmọ funrarẹ ti wa kọ iwe ranṣẹ si olu ileeṣẹ ẹgbẹ naa pe oun atawọn ọmọlẹyin oun ti ya kuro lara ẹgbẹ awakọ ero naa.
O ni igbesẹ oun atawọn ọmọlẹyin oun kaakiri idikọ to le ni igba nipinlẹ Eko naa waye lati lee gba alaafia laaye laarin oun, awọn ọmọ ẹgbẹ naa nipinlẹ Eko ati awọn alaṣẹ ẹgbẹawakọ ero naa nilu Abuja.
- 'Sanwo-Olu kan ẹbí wa lábùkù, ijó ló kí mọ́lẹ̀ kàkà kó bá wà kẹ́dùn ikú Bamise'
- Ìjọba ìpínlẹ Eko ti lé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ NURTW kúrò ní gáréèjì ọkọ̀
- Orísi ìgbésẹ̀ lá gbé kí ọ̀rọ̀ Igboho tó já sí ọ̀pẹ́ yìí, díẹ̀ rèé lára wọn- Amofin Falola
- Ǹkan yíwọ́ mọ́ onífàyàwọ́ ejo, wo ohun tó kó pamọ̀ sábẹ́ asọ
- Kà síi nípa àwọn òpópónà tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo fẹ́ tì pa nítorí ayẹyẹ ìwúyè Olubadan ní ọ̀la
- Erémọdé lásán ní Ademola Adeleke ń se, Dotun Babayemi ló máa díje dupò Osun- Kayode Oladeji
- Chidinma Ojuwu tó ń jẹ́jọ́ ikú Usifo Ataga gbadé obìnrin tó rẹwà jùlọ lẹ́wọ̀n! Ìdí rèé?
O fi kun un pe gbogbo akitiyan lati yanju aawọ laarin ẹka ẹgbẹ naa ni ipinlẹ, ati tolu ileeṣẹ rẹ l'Abuja lo ti ja si pabo.
O wa ke si gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu lati kuku ṣiṣẹ lori abala ikarun un iwe ijọba 'White paper'to jade ldun 2004 lori rọ awọn ẹgbẹ ọlọkọ ero eyi to ni ki ijọba ipinlẹ naa o gba iṣakoso awn gareeji ati idikọ gbogbo
Bakan naa lo ni ki ijọba fi ajọ iṣakoso idikọ, Park Management Committee lelẹ lati maa tukọ awọn idikọ gbogbo ni ipinlẹ naa.
O ni ajọ naa yoo wulo fun ifidimulẹ alaafia titi di igba ti wọn yoo yanju ọrọ to wa nilẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa da ọlọpaa sigboro
Nibayii naa, ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti da awọn oṣiṣẹ alaabo sigboro lati rii daju pe ọrọ idaduro alaga ẹgbẹ awakọ ero NURTW naa ko da wahala silẹ nipinlẹ Eko.
Kmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Abiọdun Alabi paṣẹ pe ki gbogbo awọn ọga ọlọpaa lẹlẹkunjẹkun o tub so okun abo ko duro daadaa lagbegbe wọn.
Ninu ifrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ mohunmaworan abẹle kan, Channels Television, ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko aṣẹ kan ti jade ki awọn ọga ọlọpaa ko ọlọpaa sawọn idkọ ero kaakiri Naijiria.
Bakan naa lo fi da awọn araalu loju pe abo to peye wa fun ẹmi ati dukia gbogbo.
Bawo ni gbogbo eyi ṣe bẹrẹ gan?
Nnkan bẹrẹ si nii wọ laarin awon adari apapọ ẹgbẹ ọlọkọ ero ni Naijiria, NURTW ati Ọgbẹni Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluọmọ to jẹ alaga ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Eko tẹlẹ nigba ti wọn fi ẹsun kan pe o n gbe awọn igbesẹ to tako aṣẹ olu ileeṣẹ ẹgbẹ naa.
Rugudu to n lọ laarin igun mejeeji yii jẹyọ ninu lẹta kan ti olu ileeṣẹ naa kọ si MC Oluọmọ pẹlu ẹsun pe ila rẹ fẹ maa ga ju onire lọ.
Lẹta naa, eyi ti akọwe apapọ ẹgbẹ NURTW lorilẹ-ede Naijiria, Alhaji Kabiru Ado Yau fọwọ si tun fi ẹsun kan MC Oluọmọ pe kaka ko tẹle ofin ẹgbẹ lẹyin ipade ti wọn ba oun atawọn ọmọ igbimọ NURTW nipinlẹ
Eko se lọjọ kẹsan an, osu keji ọdun 2022, nṣe ni Oluọmọ "bẹrẹ si ni ko awọn tọọgi rẹ lọ dun mọhuru mọ alaga tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan fawọn oni kẹkẹ marwa naa."
Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun kan an pe o kọ lati fa iṣakoso ileeṣẹ ẹgbẹ NURTW to wa lagbegbe Abule Ẹgba le igbimọ alakoso fidihẹ to wa fun awon omikẹkẹ Marwa lọwọ.
Aṣẹ ti igbimọ alaṣẹ apapọ ẹgbẹ NURTW wa fun MC Oluọmọ nigba naa ni pe ko tete tẹle aṣẹ rẹ nipa fifa akoso sẹkitariati ẹgbẹ naa tẹlẹ le alaga tuntun fun ẹgbẹ onimarwa, Azeez Abiọla lọwọ ki wakati mejidinlaadọta to pe.
Wọn tun paṣẹ pe ki o si tun ko awọn janduku to ko sawọn ẹka ẹgba naa to wa labẹ awọn ti ko ṣe tirẹ kuro ko si tọrọ aforiji lọwọ olu ileeṣẹ ẹgbẹ naa.Ẹsun miran ti wọn tun fi kan MC Oluọmọ ni pe o n lo awọn
janduku lati lọ fipa gba awọn ẹka ẹgbẹ naa to wa labẹ akoso awọn ti ko si labẹ igun tirẹ n'ipinlẹ Eko.
Ẹgbẹ́ NURTW dá MC Oluomo dúró gẹ́gẹ́ bí alága ẹgbẹ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó
Ẹgbẹ awakọ ero, National Union of Road Transport Workers, NURTW, ti kọwe idaduro fun alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya, MC Oluomo.
Owurọ Ọjọbọ, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹta, ni iroyin naa jade ninu atẹjade kan ti akọwe ẹgbẹ NURTW, fi sita.
- Chidinma Ojuwu tó ń jẹ́jọ́ ikú Usifo Ataga gbadé obìnrin tó rẹwà jùlọ lẹ́wọ̀n! Ìdí rèé?
- Yàtọ̀ sí oorun àsùn-fọnfọn, wo àwọn ìdí tóo fi nílò ìbálòpọ̀ tó gbóná-giri
- Taa ni Firdauz Abdullahi, ọmọbabìnrin Kano tí yóò di olorì tuntun fún Oluwo?
- Ọkùnrin àkọ́kọ́ tó ṣàṣeyọrí lílo ọkàn ẹlẹ́dẹ̀ láti mi ti padà kú o!
Ẹnikan to sunmọ alaga gbogboogbo ẹgbẹ naa, ti ko fẹ ka darukọ rẹ sọ fun BBC Yoruba pe lootọ ni iroyin naa.
Ninu ikede idaduro naa, wọn ni igbesẹ ọhun waye nitori bi MC Oluomo sẹ n tapa si ofin awọn adari, to n hu iwa tani yoo mu mi, to si tun n kọ ẹyin awọn ọmọ abẹ rẹ nipinlẹ Eko si awọn alaṣẹ loke.
Eyi n waye lasiko ti idarudapọ n waye laarin ẹgbẹ awakọ NURTW ati TOOAN to jẹ ẹgbẹ awọn to n wa kẹkẹ Maruwa nipinlẹ Eko.
Awọn alaṣẹ sọ pe awọn da MC Oluomo duro nitori ki rogbodiyan ma baa waye, lẹyin ti awọn gbọ̀ iroyin pe o ti n ru awọn ọmọ ẹgbẹ soke lodi si awọn alaṣẹ.
Wọn ni igbesẹ naa tako ofin ẹgbẹ NURTW.
Bakan naa ninu ikede idaduro to wa loju opo Facebook wọn ni NURTW ti sọ pe ki Ọgbẹni Musiliu ko gbogbo dukia ẹgbẹ to wa lọwọ rẹ silẹ fun igbakeji rẹ, ki ipo olori ma baa ṣófo.