Chidinma Ojukwu crowned Miss Cell: Ọ̀dọ́bìnrin tó ń jẹ́jọ́ ikú Usifo Ataga gbadé obìnrin tó rẹwà jùlọ lẹ́wọ̀n Kirikiri

Iroyin ti n gbode kan eyi to n ṣafihan pe arabinrin Chidinma Ojukwu ti wọn fi ẹsun ipaniyan kan gba ade obinrin to rẹwa ju lgba ẹwọn to wa.

Chidinma ni wọn fi ẹsun kan pe o pa arakunrin Michael Ataga to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ amohunmaworan Super Tv.

Chidinma wa ni ẹwọn Kirikiri nibi ti o ti dije to si jawe olubori gẹgẹ bi arẹwa obinrin to dangajia ju eyi ti wọn pe ni "Miss Cell".

Idi niyi ti BBC ṣe kan si agbẹnusọ ọgba ẹwọn naa, Ọgbẹni Rotimi Oladokun to si ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ.

"Ohun to ṣẹlẹ ni pe lati lee ṣe ayọjọ ọjọ obinrin lagbaye, awọn eto kan waye ninu agbala ọgba ẹwọn, awọn ẹgbẹ ẹlẹwọn kan ṣe ere ori itage nigba ti awọn kan ṣe irin oge".

O ṣalaye pe nitori naa ni oniruuru afihan wa lati awọn igun ẹgbẹ ẹlẹwọn ti awọn to jawe olubori naa si wa nibi eto ọhun.

"Ọkan lara awọn ẹlẹwọn ni Chidinma jẹ tori naa a o le ni ko ma kopa nitori ẹsun ti wọn fi kan an atipe, igun ti wọn pin in si ṣe irin oge, bo ṣe jẹ niyẹn".

Agbẹnusọ fun ọgba ẹwọn ọhun sọ pe awọn ẹlẹwọn tọ ọọfisa to wa lnu iṣẹ iṣakoso pe awọn fẹ yẹ ayajọ ọjọ awọn obinrin lagbaye si wọn si ri aṣẹ "ẹ tẹsiwaju" gba.

"Koda lara awọn ẹlẹwọn jẹ oriṣiriṣi ẹbun bii owo ẹkọ atawọn nkan mii".

Awọn aworan to wa kaakiri lori ayelujara ṣafihan bi awọn arabinrin kan lara wọn naa ṣe fi orin da awọn eeyan lara ya ti eto igbade naa si waye fun Chidinma Ataga.

Ibi tí ìjẹ́jọ́ Chidinma Ojukwu dé dúró

Eeyan mẹfa lo ti kawọ pọnyin niwaju adajọ lati jẹrii lori ẹjọ naa lati igba to ti bẹrẹ.

Chidinma n foju wina ofin lori ẹsun pe o pa oludasilẹ ileeṣẹ Super Tv, Usifo Ataga to si jẹ pe o n sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Adebayo Quadri ni ẹnikeji toun naa n jẹj lori ẹsun yii latari pe wọn fẹsun kan o padi apo pọ pẹlu Chidinma Ojukwu ninu ipaniyan naa.

Ẹsun mẹjọ ni awọn afurasi mejeeji yii n jẹjọ le lori latorii igbimọ pọ paniyan, gigun eeyan lọb, yiyi iwe, ole jija ati ṣiṣe ẹda iwe atẹjade banki.

Bakan naa, ọwọ tẹ aburo Chidinma toripe o gba ẹrọ ibanisọrọ Iphone 7 to jẹ ti Ọgbẹni Ataga.

Lafikun, arabinrin kan, Nkechi Mogbo ati Abubakar Dauda ti wọn jẹ onile ti Ataga ya gbe fun igba ranpẹ to fi mọ ẹṣọ ile naa ti wn ti oku Usifo Ataga naa ti jẹrii nipa ohun ti wọn nipa iṣẹlẹ naa.

One Nkechi Mogbo and Abubakar Dauda, di owner of di short stay apartment and di security guard wia dem find Usifo Ataga deadi bodi don stand as witness to tok wetin dem know about di mata.