You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Female army proposal from corps member: Iléèṣẹ́ ológun fi sọ́jà obìnrin sí àtìmọ́lé nítorí pé kọ́pà fún un ní òrùka ilérí ìgbeyàwó ní Kwara
Ileeṣẹ ologun Naijiria sọ pe lootọ ni oun fi obinrin sọja kan si atimọle, nitori pe o gba oruka ileri igbeyawo lọwọ agunbanirọ kan ni ibudo awọn agunbanirọ nipinlẹ Kwara.
Ọjọ diẹ sẹyin ni fidio kan to ṣafihan obinrin sọja naa ati agunbanirọ kan to jẹ ọkunrin jade sori ayelujara.
Ninu fidio naa ni ọmọkunrin agunbanirọ ọhun ti kunlẹ, to si fun obinrin naa ni oruka ileri igbeyawo, ti wọn n pe ni marriage proposal ni ede Gẹẹsi.
Inu aṣọ ologun ni obinrin naa wa, ti ọkunrin naa si wa ninu aṣọ ajọ NYSC.
- Òhun tí Cute Abiola ṣe rèé táa fí sọ ọ́ sí àhámọ́ - Iléeṣẹ́ Navy
- Cute Abiola: A ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò ni, ẹ máa rétí àwọn "Skits" tó gbaski
- Àwọn agbébọn ti yìnbọn pa èèyàn 38 ní Kaduna
- Àwọn ọlọ́pàá ti gbé tọkọtaya tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó fi ọmọ oṣù mẹ́fà dí gbèsè tó fi kú
- Ó ti ṣe díẹ̀ tí mo ti ń gbé pẹ̀lú ìbànújẹ́, ayé ti sú mi - Ibrahim Chatta
Botilẹ jẹ pe a ko ti mọ orukọ obinrin sọja naa, ileeṣẹ ologun sọ pe o tapa si ofin to de awọn ọmọ ogun nipa bo ṣe n rinrinajo ifẹ pẹlu ẹni to n kọ iṣẹ labẹ rẹ.
Ni ibudo ti awọn agunbanirọ to n sinru ilu ni Naijiria maa n wa fun ọsẹ mẹta akọkọ, awọn ọmọ ogun lo ma n kọ wọn ni oriṣiriṣi awọn ilana idaabo bo ara ẹni, to fi mọ ilana ogun jija.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun Naijiria, Ọgagun Agba Onyema Nwachukwu sọ pe obinrin sọja naa lo agbara ipo rẹ lori agunbanirọ ni, eyi to tako iwa ọmọluabi iṣẹ ologun.
Ọgagun Nwachukwu sọ pe ofin meji lo rú - akọkọ ni pe o tapa si ofin to de lilo ori ayelujara ibaraẹnidọrẹ, ati ikeji to jẹ ṣiṣe ere ifẹ lasiko to wa ninu aṣọ ologun.
"Nitori naa, o ni lati gba ibawi."