You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Yoruba Nation: Ẹgbẹ́ Afenifere kò gbàgbọ́ nínú yíyapa kúrò ní Naijiria - Ayo Adebanjo
Ẹgbẹ Afenifere ti sọ pe oun ko gbagbọ ninu yiyapa ati titu orilẹ-ede Naijiria ka.
Ẹni to jẹ adele oludari ẹgbẹ naa, Oloye Ayo Adebanjo, lo sọ ọrọ naa fun awọn akọroyin nilu Eko.
Iwe iroyin Premium Times jabọ pe Olye Adebanjo sọ pe ẹgbẹ naa gba pe awọn olori ijọba ti ilu dibo yan wa ni iṣakoso Naijiria, eyi ti ko fi le mu ki awọn o jẹ oluyapa.
Oloye Adebanjo sọ pe nkan ti ẹgbẹ Afenifere n fẹ ni ki aarẹ o ṣe idasilẹ ijọba gbogboogbo ti yoo ṣe atunto orilẹ-ede Naijiria, ni ibamu pẹlu ifẹ ọkan araalu.
- Ó ṣe é ṣe ká má kópa nínú ìdìbò 2023 tí àtúntò Naijiria kò bá wáyé - Afenifere
- Tinubu, àtúntò Nàíjíríà ni ko wá ná, ko tó du ipò ààrẹ - Pa Adebanjo
- Àjọ tó ń mójútó pínpín iná ọba fikún owó 'Metre' k'áráàlù lè sáré tete lọ gba 'Prepaid'
- Ìjọba Buhari, tí ẹ bá fẹ̀ yanjú ọ̀rọ̀ yìí ẹ jẹ́ kí Igboho lọ tọ́jú ara rẹ̀ ní Germany ná - Agbẹjọ́rò
- Akeredolu kéde òfin kónlé-ó-gbélé ní Igbara-Oke torí rògbòdìyàn lórí ìbò kánsílọ̀
- Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lu $16b àti €1bn tí Ààrẹ Buhari fẹ́ ya
Bakan naa lo sọ pe ki ipade apero gbogboogbo waye lori atunto, ti Naijiria si gbọdọ pada si ṣiṣe amulo ofin ọdun 1960 to wa lasiko ominira, ko to o di pe idibo ọdun 2023 waye.
O ni"Naijiria tiofin naa gbekalẹ ni eyi to n bọwọ fun ẹtọ gbogbo ẹkun to sopọ di ẹyọkan."
Adebanjo sọ pe ko le si alaafia nibi ti ko ba ti si ibaraẹni dọgba, idajọ ododo ati otitọ to ni ipinlẹ rere ninu atunto orilẹ-ede.
O wa fikun ọrọ rẹ pe ẹgbẹ Afenifere yoo ṣe atilẹyin fun ẹnikẹni to ba ni oye to kun nipa atunto Naijiria, to si ṣetan lati sẹ ijọba to ko gbogbo eeyan mọra.