Ẹgbẹ́ Afenifere sọ pé kíkúrò Buhari nípò ní 2023 lọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìṣòro Naijiria

Ẹgbẹ Afenifere ti sọ pe ko si ni ikapa Aarẹ Muhammadu Buhari tabi ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, lati yanju awọn iṣoro to n dojukọ Naijiria.

Adele Olori ẹgbẹ naa, Oloye Ayo Adebanjo sọ fun awọn akọroyin nile rẹ to wa niluu Ijebu-Ode pe awọn ti sọ ireti nu pe Buhari yoo yanju awọn iṣoro naa.

O ni kikuro nipo rẹ nikan ni yoo fi opin si wọn.

Oloye Adebanjọ sọ pe o ṣe e ṣe ki ẹgbẹ Afenifere o ma darapọ mọ idibo ọdun 2023, ti ko ba fi si atunto Naijiria ko to di asiko naa.

Nigba ti oun naa ba awọn akọroyin sọrọ, Akọwe ikede fun ẹgbẹ Afenifere, Jare Ajayi, sọ ninu atẹjade kan pe, eto aabo to dara gbọdọ tete wa fun awọn eeyan to n gbe ni awọn ilu kan nilẹ Yoruba, paapaa Yewa nipinlẹ Ogun, ati Oke Ogun nipinlẹ Oyo.

O ni ikọlu awọn darandaran ti mu ki awọn to n gbe ni agbegbe naa ma a salọ si orilẹ-ede Benin ati awọn orilẹ-ede miran to sunmọ Naijiria.

Bakan naa lo sọ pe Afenifere faramọ ipinnu awọn gomina ilẹ Yoruba lati fi ofin de dida ẹran kaakiri ilu, ati idasilẹ ikọ alaabo Amotekun.

O ni o ṣe pataki ki ijọba Naijiria tete wa ojuutu si igbesunmọmi, ijinigbe ati ija to n waye ni gbogbo igba laarin awọn agbẹ ati darandaran.