You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ondo curfew: Ìjọba kéde òfin kónlé-ó-gbélé ní Igbara-Oke lẹ́yìn tí rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ lórí ìbò kánsílọ̀
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kede ofin konle-o-gbele ọlọjọ kan niluu Igbara-Oke tii ṣe ibujoko ijọba ibilẹ Ifedore nipinlẹ naa.
Gomina Akeredolu kede ofin konle-o-gbele nibẹ lẹyin ti rogbodiyan bẹ silẹ lori esi ibo kansilọ to waye ni ijọba ibilẹ naa.
Akọwe iroyin fun gomina Ondo, Richard Olatunde, lo fi ọrọ naa lede niluu Akure.
- Ẹ yéé gbé ìròyìn òfegè kiri nípa olóògbé Femi Osibona, ó ṣèlérí N25M fún ìjọ mi àmọ́... - Genesis
- Oluwo dá èsì ńlá padà fún àwọn olórìṣà tó ní kò tọ́ síi kó ní Ọba Yorùbá kìí ṣe ìgbákejì Òrìṣà
- Oluwo ti yó tán, ó ń wá bẹ́kùn bẹ́kùn kiri, àwọn òrìṣà tó ń tàbùkù ṣì ń wò ó lọ́wọ́- Ọba Ogboni ìwásẹ̀
- Ìjọba Buhari, ẹ jẹ̀kí Sunday Igboho lọ tọ́jú ara rẹ̀ ní Germany ná tí ẹ bá fẹ̀ yanjú ọ̀rọ̀ yìí- Agbẹjọ́rò
- Wọ́n ta ìkókó ọmọ mi ní N1M, wọ́n gbé abirùn ọmọ lé mi lọ́wọ́ - Obìrìn aláàrùn ọpọlọ figbe ta
- Wọ́n tún ti yọ òkú èèyàn méjì síi níbi ilé tó wó l'Eko, ó di èèyàn 45 tó kú níbẹ̀ báyìí
- Tí ó kó bá sùn ní aago yìí sí aago yii, àkóbá tí ò ń ṣe fún ìlera ọkàn rẹ nìyìí
- Bó ṣe òṣèlú náà ló gbà, a léè fi wo ọ̀rọ̀ Sunday Igboho - Abubakar Malami
Akeredolu ni aṣẹ naa ti mulẹ nin kiakia, bakan naa lo paṣẹ fawọn oṣiṣẹ eleto abo lati ri pe awọn araalu tẹ le ofin konle-o-gbele ọhun ki alaafia le jọba.
Gomina ipinlẹ Ondo tun rọ awọn ọba alade atawọn alẹnulọrọ to fi mọ gbogbo awọn tọrọ kan lati kilọ fawọn ọmọlẹyin wọn pe ki wọn ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.
Gomina Akeredolu ni ijọba ko ni fi oju 're wo ẹnikẹni to ba tapa si ofin konle-o-gbele naa.
Ifẹhonuhan lo kọkọ bẹrẹ niluu Igbara Oke lẹyin eto idibo kansilọ to waye ki ọrọ naa to di nla.