You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sunday Igboho linked with Boko Haram Sponsor: Ẹgbẹ́ Ilana omo Oodua ní ìjọba ń gbìyànjú láti dẹ́rù ba ẹ̀yà Yoruba ni
Agbarijọpọ awọn ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹ-ede Yoruba, Ilana Omo Oodua (IOO) ti ṣapejuwe ẹsun igbesunmọmi ti ijọba Naijiria fi kan Sunday Adeyemo Igboho, gẹgẹ bi ọrọ oponu ati nkan to pa ni lẹẹrin.
Wọn ni igbiyanju lati tabuku ijijagbara awọn eeyan Yoruba labẹ ofin ni igbesẹ ijọba Naijiria.
Ọjọ Ẹti ni Agbẹjọro Agba ni Naijiria, to tun jẹ Minisita fun eto idajọ, Abubakar Malami, sọ pe Sunday Igboho ni ibaṣepọ pẹlu awọn to n ṣagbatẹru igbesunmọmi ni Naijiria. Bakan naa lo sọ pe aṣofin agba kan lo n ko owo fun Igboho lati maa gbesunmọmi.
Lara ẹsun igbesunmọmi ti wọn fi kan Igboho ni pe o fi owo ranṣẹ si ẹnikan to jẹ alabarin ọkunrin kan, Saurajo Abubakar Muhammad, ti wọn ran lọ si ẹwọn nilu Dubai nitori igbesunmọmi.
Ṣugbọn ninu atẹjade ti Akọwe ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, Ọgbẹni Maxwell Adeleye, fi sita ni lori ẹsun naa, o ni ẹsun naa ko lẹsẹ nilẹ rara, to si jẹ ọna lati dẹru ba ijijagbara awọn ọmọ Yoruba.
"A ti ka atẹjade ti Malami fi sita fun ijọba Naijiria, a si ri i pe ko si ibi kan ninu atẹjade naa to fihan pe Sunday Igboho ni nkan ṣe pẹlu igbesunmọmi."
- Àwọn agbébọn ya wọ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Oyo, wọ́n tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀
- Ṣé lóòtọ́ ni Sunday Igboho ń gbowó ìgbésùnmọ̀mí lọ́wọ́ agbódegbà Boko Haram kan gẹ́gẹ́ bí Malami ṣe sọ?
- Sunday Igboho fún Abubakar Malami àti ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà lési ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí tí wọ́n fi kàn án
- Kéére o! Ìjọba tú òbìnrin kan ṣoṣo amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sunday Igboho tó kù láhàmọ́ DSS silẹ̀
- Irú àìsàn wo ló ń bá Sunday Igboho finra ní Benin kí sì ní àwọn àgbààgbà Yorùbá n sọ sí ọ́rọ́ yi?
- Ọ́ọ́físà tó lu Clement awakọ̀ Uber níbi EndSARS gba ìwé máa lọ ilé ná
O ni nkan ti awọn ri ka ni pe Igboho fi miliọnu mejila ati ẹgbẹrun lọna ẹgbkẹrin din aadọta Naira ranṣẹ si Abdullahi Usman, to jẹ ọrẹ ẹni ti wọn ju si ẹwọn fun igbesunmọmi.
Ẹgbẹ IOO sọ pe oniṣowo ọkọ ni Sunday Igboho, to si ma n ni nkan ṣe pẹlu awọn to n ṣẹ owo Naira si ti ilẹ okeere, gẹgẹ bi awọn oniṣowo ṣe ma n ṣe.
Ẹgbẹ naa sọ pe nkan to pani lẹrin ni ẹsun yii.
Lori ti aṣofin ti wọn lo n fi owo ran Igboho lọwọ, ẹgbẹ IOO sọ pe ọdun 2013 ni ọrọ fifi owo ranṣẹ laarin aṣofin naa ati ileeṣẹ Sunday Igboho, Adesun International Concept Ltd, ti waye, ṣaaju ki ipolongo idasilẹ Yoruba Nation to o bẹrẹ ni ọdun 2019.
Wọn ni gẹgẹ bi oniṣowo ọkọ, ẹnikẹni lo le ra ọja lọwọ rẹ.
Ọgbẹni Adeleye gba Abubakar Malami ni imọran pe ko lo okun ati agbara rẹ lati fi ṣe eto bi awọn eniyan Gusu yoo ṣe ni orilẹ-ede ti wọn.