You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mike Bamiloye àti Gloria ìyàwó rẹ́ ṣe àjọyọ̀ ọdún 33 tí wọ́n ṣe ìgbéyàwó
Ajihinrere Mike Bamiloye ti sọ pe ọpẹlọpọ Ọlọrun ti ko jẹ ki awọn obinrin ti oun kọkọ dẹnu ifẹ kọ gba lati fẹ oun.
Ninu ọrọ kan to kọ si ori ayelujara Instagram lati ṣajọyọ ọdun mẹtalelọgbọn ti oun ati iyawo rẹ Gloria ti ṣe igbeyawo.
O ni lọjọ ayẹyẹ igbeyawo oun, ni ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 1988 ni ẹnikan to jẹ ọmọ ẹgbẹ ori itage oun nigba naa sọ fun oun pe "igbeyawo yii ni ibẹrẹ iṣẹ iranṣẹ wa".
O ni eyi jẹ lẹyin ọdun mẹta ti oun ti da iṣẹ iranṣẹ ere ori itage silẹ.
Ṣaaju asiko naa, lo ni ẹnikan ti kọkọ sọ fun un pe ọjọ ti oun ba ṣe igbeyawo ni iṣẹ iranṣẹ oun yoo bẹrẹ lọtun.
Bamiloye sọ pe ọrọ naa ko tete ye oun, afi igba ti oun bẹrẹ si ni ni oriṣiriṣi iriri.
"Lonii, ti igbeyawo wa to bẹrẹ ni ọdun mejilọgbọn sẹyin, pe ọgbọn ọdun, mo le fi igboya sọ pẹlu òye pe laisi Gloria Olusola Alaba, mi o le ni iṣẹ iranṣẹ ti yoo ni aṣeyọri".
O tẹsiwaju lati sọ pe kani kii ṣe pe Ọlọrun ṣaanu fun oun ni, ti ko si jẹ ki "awọn ọmọge ti mo ti kọkọ dẹnu ifẹ kọ gba fun mi, igbeaye mi kò bá daru titi lai, nitori pe mi o ni le fẹ Gloria".
Agba ajinhinrere naa sọ pe lootọ ni oun ro pe Ọlọrun n binu si oun ni awọn obinrin ko ṣe gba lati fẹ oun, lai mọ pe Ọlọrun n ṣeto ọjọ iwaju oun ni nipa didari oun si ọdọ egunegun iha oun gan-an-gan.