You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Chiwetalu Agu arrested by Army: Kí ni òṣèré yìí ṣe tí àwọn ológun gbé e jàǹtò? Ẹṣẹ tí wọn kà síi lọrùn rèé
Gbajugbaja oṣerekunrin, Chiwetalu Agu ti gbominira lẹyin ti awọn sọja mu u lọjọ Ọjọbọ, ọjọ keje, oṣu Kẹwaa.
Akẹẹgbẹ rẹ, Destiny Etiko lo fi iroyin naa sita loju opo Instagram rẹ pe "Wọn ti tu Uncle Chiwetalu Agu silẹ...Ọlọrun o ṣeun."
Oṣerebinrin miran, Chizzy Alichi naa fidirẹmulẹ pe wọn ti tu u silẹ, to si wa ni alaafia.
Ṣugbọn, ileeṣẹ ologun ko ti i fi ikede sita boya wọn ti tu u silẹ.
- Òní lòní ń jẹ́, pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ayẹyẹ ọdún ìbéjì yóò wáyé nílùú Igbo-Ora
- Bí a kò bá yá owó, Nàìjíríà ò bá má bọ́ nínú ìfàsẹ́yìn ọ̀rọ̀ ajé - Mínísítà ètò ìsúná
- Mo dúpẹ́ pé Ọlọrun kò jẹ́ kí àwọn ọmọge tí mo kọ́kọ́ dẹnu ìfẹ́ kọ gbà láti fẹ́ mi - Mike Bamiloye
- Ṣé o mọ̀ pé o leè kó Covid pẹ̀lú ọmọ ìka ẹ̀sẹ̀ rẹ̀ láì mọ̀?
- Òrùka ìgbéyàwó,ìlẹ̀kẹ̀ ìdí àti àwọn nkán míràn tàwọn eléwé ọmọ fí n ṣètò ìfètòsọ́mọbíbí
Kí ni òṣèré Chiwetalu Agu ṣe tí àwọn ológun gbé e jàǹtò? Ẹṣẹ tí wọn kà síi lọrùn rèé
Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ti sọ pe lootọ ni awọn fi ọwọ ofin mu gbajugbaja oṣere Chiwetalu Agu.
Gẹgẹ bi atẹjade ti awọn ologun fi sita lati olu ileeṣẹ wọn, wọn muu toripe wọn ni o n ko awọn ọmọ kgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹede Biafra (IPOB) jẹ to si n ṣe atilẹyin fun wọn.
Wọn fi kun un pe awọn gba oṣere naa mu nigba to wọ aṣọ ti wọn ran pẹlu awọ asia ẹgbẹ Biafra, wọn si gbee lati fi ọrọ waa lẹnu wo.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ni o n kọjalẹ ko fẹ fi wọn fi ọwọ ipa mu oun, ṣe ni wọn gbee janto lọ si atimọle wọ amọ wọn ni awọn ko fiya kankan jẹẹ.
Bakan na ninu atẹjade awọn ologun, wọn ni awọn bọwọ fun ẹtọ awọn araalu gẹgẹ bo Se wa ninu ofin ilẹ Naijiria bẹẹ naa si ni awọn koro oju si ki ẹnikẹni tẹ ẹtọ eeyan loju mọlẹ tabi ko ẹgbẹ jọ lati ru ofin.
- Àwọn Òṣèré fíìmù Yorùbá tẹ́ ò ro tó tí jápaa lọ ìlú Òyìnbó rèé
- Obìnrin tó bá ń gbé bùkátà kò ní ọkọ kódà kó wà nílé ọkọ - Kemi Afolabi
- 'Eniola Badmus wọ pátá lọ sí ààfin Oba Elegushi, "ọ̀ín" kí ló burú níbẹ̀?'
- Kókó mẹ́rin tó jẹyọ lẹ́yìn ìpàdé àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP
- Àwọn Òṣèré fíìmù Yorùbá tẹ́ ò ro tó tí jápaa lọ ìlú Òyìnbó rèé
- Tọkọ-taya kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹun tán ní Ọjọ́ Àyájọ́ Ọ̀mìnira Nàíjíríà
Eleyi waye gẹgẹ bi fidio kan ṣe jade nibi ti awọn ọkunrin kan to wọ aṣọ ologun da gbajugbaja oṣere naa, Chiwetalu Agu duro ni Onitsha, ipinlẹ Anambra.
Nigba naa ni iroyin bẹrẹ si ni tan ka pe awọn ologun ti gbe oṣere naa.
Ninu fidio naa, awọn ologun kan da bọọsi kan ti wọn kọ Chukwuetalu films si lara wọn si wọ oṣere naa bọlẹ titi ti ero fi tu jade afigba ti iro ibọn le wọn sa lọ.
Loṣu to kọja ni ọrọ Agu gba ori ayelujara kan tori pe o wọ aṣọ kan ti wọn fi asia Biafra ran.
Ta ni Oṣere Chiwetalu Agu?
Chiwetalu Agu to jẹ gbajugbaja ni ọpọlọpọ mọ si Ichie Ogwu, eekan si ni lagbo oṣere Nollywood to tun jẹ adẹrinpoṣonu.
Oṣere naa jẹ ọmọ ilu Enugu ni iha Guusu-Ila Oorun to si ti bẹrẹ ere sinima tipẹ tipẹ ki Nollywood tilẹ to bẹrẹ.
O ti kopa ninu ọpọlọpọ fiimu bii Taboo, Wedding Party apa keji.
Agu gbajumọ gidi gan fun awada ṣiṣe pẹlu awan oriṣiriṣi ọrọ ẹna to maa n ti ẹnu rẹ jade eyi to mu ki gbogbo ẹya fẹran lati maa wo ere rẹ gan to fi mọ ẹya Yoruba.
Ọpọlọpọ yoo tun ranti rẹ daadaa fun ipa oloye tabi baale ile to buru tabi to maa n ṣe ika ninu sinima.