World Twins Festival, Igbo-Ora: Ayẹyẹ ọdún ìbejì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú síse ọbẹ̀ Ilasa

Wọn ti bẹrẹ si n pese eto ọbe Ilasa bayii niluu Igbo-Ora.

Ọbẹ yii ni igbagbọ wa pe o maa n jẹ ki awọn obinrin wọn bi ibeji, eyi to mu ki ilu naa jẹ ilu ti wọn ti n bi ibeji julọ lagbaye.

Lara awọn ohun elo ti akọroyin BBC ti foju ganni nibẹ ti wọn fi se ọbẹ naa ni ẹfọ ti wọn n pe ni ewe ila, ẹgusi, iru, epo, atawọn nnkan mi ti wọn fin se ọbẹ nilẹ Yoruba.

BBC Yoruba ti wa nikalẹ niluu Igbo-Ora lati maa mu gbogbo ba ba ṣe n lọ wa si eto igbọ ati oju iworan yin.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣeyin?

Òní lòní ń jẹ́, pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ayẹyẹ ọdún ìbéjì yóò wáyé nílùú Igbo-Ora

Nje ẹ mọ pe ilu kan wa ni orilẹ-ede wa nibiti bibi ibeji ti pọ ju?

Ṣe ko jẹ kayeefi pe ọpọlọpọ ile ni o jẹ ile ibeji ninu ilu naa?

Igbo-Ora jọ ilu to kun fun ọpọlọpọ ohun meriri ni orilẹ-ede Naijiria, nibi ti awọn oyinbo ti ṣe awari ibeji nigba mẹrindinlogun, nibi ikunlẹ ẹgbẹrun.

Ilu yii kan naa ni awọn ara Amẹrika ti ṣe awari ibeji ni ikunlẹ mẹtalelọgbọn ni ikunlẹ ẹgbẹrun.

Ilu Igbo-Ora to wa ni orilẹ-ede Naijiria tun ṣe awari ibeji nigba aadọta ni ikunlẹ egberun.

Oniwadii Patrick Nylander lo fidi awari rẹ mulẹ nigba to rinrinajo lọ si ilu Igbo-Ora.

Ilu Igbo-Ora ni jẹ ogoje kilomita lati Ilu Eko, o si jẹ olu ilu fun awọn ibeji ni agbaye.

Ibeji wọn pọ ni ilu Igbo-Ora ju ilu miran lo lagbaye, iwadii fi mulẹ pe, arinrinjo ninu ilu naa le fẹ dojuru fun alejo nigba to ba pade oniruru awọn ti wọn jọ ara wọn nitori ile kọọkan lo ni ibeji larin wọn.

E bawa kalọ nigba ti a ba darapọ fun pọpọṣinṣin ọdun ibeji ti ọdun 2021, nibi ti a oo ti mu ara ọtun ninu aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba wa fun yin, ati pataki ọdun ibeji ni ilẹ kaarọ oojiire.