Benue Protest: Àwọn olọ́kadà ti gba àwọn ìyàwó wa tán nítorí a kò lówó lọ́wọ́- Àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ni Benue

Àwọn òṣìṣẹ́ fẹyinti kan ni ipinlẹ Benue ti gúnlè ìwọ́de lòdì sí bí ìjọba ipinlẹ naa ṣe kọ lati san awọn owo oṣu àti ajẹmọnu wọn fún nnkan bíi ọdún mẹta.

Wọn bẹrẹ ifẹhonuhan náà láti agbegbe Ken Ville Park, ni High Level, wọn sì lọ káàkiri ìlú ti wọn sì ni kọ onírúurú orin.

Alaga ẹgbẹ àwọn òṣìṣẹ́ fẹyinti náà, Akosu Ugba sọ fún àwọn akọroyin pé àwọn n ṣe ìwọ́de náà láti bere ẹtọ awọn lọwọ ìjọba, ati pe ki awọn aráàlú lè mọ ohun ti wọn n dojukọ.

Ọ ni "A fẹ kí gbogbo àgbáyé mọ pé ebi n pa wa, ìyá si n jẹ wá."

Alaga ni: "Ohun tó n ṣẹlẹ sí wa jẹ ifiyajẹni lọna àìtọ́ nitori a kò tíì gba owo oṣù lati nnkan bíi ọdún mẹta o le."

Arakunrin naa tẹsiwaju pe "Awọn ọmọ wa ko le lọ ile ẹkọ mọ nitori a kò rí owo san, awọn ọlọkada sí ti gba awọn ìyàwó wa nitori a ko lowo lọwọ."

Gẹgẹ bíi ohun tó sọ, púpọ nínú wọn ló dubulẹ àìsàn ṣugbọn ti kò ri owó láti tọju ara rẹ.

Ọ fi kun pe nnkan bíi ẹẹdẹgbẹta lara wọn lo ti kú láì rí ẹtọ wọn gbà lọwọ ìjọba.

Lẹyìn náà ló rawọ ẹbẹ sí ìjọba láti boju aanu wo awọn ki wọn ma ba a ku sinu iṣẹ.