WhatsApp down: Àwọn ẹ̀rọ ìléwọ́ tí kò ní bá WhatsApp ṣiṣẹ́ mọ́ rèé bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kínní, oṣù tó ń bọ̀

Ileeṣẹ Facebook ti kede pe oju opo atẹjiṣẹ WhatsApp ko ni ṣiṣẹ mọ lori awọn ẹrọ ilewọ kan bẹrẹ lati oṣu kọkanla ọdun 2021 yii.

O ni awọn yoo dẹkun iranwọn ṣiṣe fun awọn eeyan to ba n lo awọn ẹrọ ilewọ naa, awọn ko si ni gba ki irufẹ awọn ẹrọ ilewọ bẹẹ maa lo oju opo atẹjiṣẹ WhatsApp.

Eyii to n tumọ si pe pupọ ninu awọn to n lo irufẹ ẹrọ ilewọ bẹẹ yoo nilo lati lọ ra ẹrọ ilewọ miran.

Ileeṣẹ to n ṣe iwadii nipa imọ ẹrọ, TitanTech sọ ninu atẹjade kan pe oniruru ẹrọ ilewọ bii ogoji ni WhatsApp ko ni ba ṣiṣẹ mọ.

TitanTech ni awọn to n lo Android 4.1 sisalẹ atawọn ti wọn n lo iOS 10 sisalẹ ko ni lanfaani lati lo WhatsApp lori foonu wọn.

iPhone

Fun awọn to n lo iPhone, WhatsApp yoo kọ iṣẹ lori awọn ẹrọ ilewọ iPhone 4 sisalẹ.

To n tumọ si pe awọn to n lo iPhone 4S, iPhone 5, iPhone 5S, iPhone 6, ati iPhone 6S gbọdọ ṣe imudojuiwọn ẹrọ ilewọ wọn si iOS 9 tabi ju bẹẹ lọ ki WhatsApp to le maa ṣiṣẹ lori ẹrọ ilewọ wọn.

Andoid

Ileeṣẹ Facebook ni WhatsApp yoo kọ iṣẹ lori awọn ẹrọ ilewọ to ba n lo Android 4.0.3 sisalẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ ẹrọ ibaraẹnisọrọ ni ọpọn wọn ti sun kuro lori Android 4.0.3, awọn ẹrọ ilewọ kan bii HTC Desire, LG Optimus Black, Motorola Droid Razr, Samsung Galaxy S2 ati S3 ṣi n lo Android 4.0.3.

WhatsApp ti wa kede pe awọn eeyan gbọdọ maa lo ẹrọ igbalode to ba oju opo awọn mu ki wọn to le maa gbadun oju opo naa daadaa.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ bii melo ka sẹyin ni Facebook, WhatsApp ati Instagram dede kọṣẹ kaakiri agbaye fun nnkan bii wakati meje gbako.

Ọpọ ileeṣẹ lo padanu obitibiti owo lasiko ti awọn oju opo naa daṣẹsilẹ, koda Facebook funra rẹ gan ko gbẹyin.

Òṣìṣẹ́ ile isẹ Facebook tẹ́lẹ̀ rí ti tú àṣírí kan fún àwọn olóṣèlú pe ojú òpó àtàwọn itakun ilé isẹ awọn n fọwọ́ tọ ìlera inú ọpọlọ àwọn ọmọdé ó sì ń fà iyapa láwùjọ.

Frances Haugen to jẹ alakoso ọjà to ti fi ise silẹ di ajafẹtọ yii ń sọ eyi fun awọn olóṣèlú orile-ede Amẹrika to si bu ẹnu atẹ gidi lu ileese náà níbi ìpàdé ile igbimọ aṣofin kan to waye.

Lẹ́nu lọọlọ yii, ileese Facebook ń lá ayẹwo kọja àti oniruuru ipe fún amojuto awọn isẹ wọn.

Oludasilẹ Facebook, Mark Zuckerberg naa ti wá fèsì pada to ni ẹ̀sùn yii ko jọ ọ rara kò sì sí ní ìbámu pẹlu afojusun ileese naa.

Ninu atejade kan fi ranṣẹ yika awọn oṣiṣẹ rẹ, o ni ọpọ ọrọ ti Haguen sọ ko mu ọpọlọ dani to si ni dipo bẹ́ẹ̀, Facebook n ṣe akitiyan lati gbogun ti awọn nkan to lee ṣakoba.

"A ni ifẹ si ohun tó ba nii ṣe pẹlu aabo ati ìlera ọpọlọ eeyan", Zuckerberg fi ọrọ yii jáde soju opo Facebook rẹ. Ó nira láti ri eto to n pa ojú ìtumọ̀ isẹ wa àti erongba wa da si nkan mii.

O ni Facebook ni ojú òpó itakun agbaye to gbajumọ ju lagbaye. Ileese náà ni oṣooṣù làwọn ń ní ero to to 2.7 bilionu to n lọ ojú òpó náà dáadáa.

Bákan náà ni ọgọọrọ eeyan lo n lo awọn itakun agbaye wọn míì bíi Whatssap àti Instagram.

Àmọ́ wọn ti kojú onírúurú ẹjọ́ káàkiri lórí kíkúnná nínú pipin ìròyìn kárí dáadáa.

Arábìnrin Haugen to n bù ẹnu atẹ lu isẹ wọn gbóríyìn fún bí Facebook, Instagram àti Whatssap ó ṣe ṣiṣẹ́ lọjọ Aje.

O ni "mi o mọ ìdí tó fi ṣẹlẹ̀ sugbọn mo mọ pe fún wákàtí to le ni márùn-ún, wọn o ribi lo Facebook láti fi dá iyapa silẹ, da ijọba ru tabi jẹ ki awọn ọ̀dọ́bìnrin fojú tembelu ara wọn".

Haugen sọ fún àwọn Sẹnetọ pé "a gbudọ gbé ìgbesẹ nísinsìnyí".

Ní ti Zuckerberg, ó ni ìwádìí nípa Instagram fihan pe awọn ọdọkunrin n kọ ẹ̀kọ́ gidi nipa lilo oju opo naa. "Ohun to kan ṣe pataki fún mi ni pe gbogbo ohun ti a ṣe dara fún àwọn ọmọdé".

Lori èyí, ati awọn Ṣeneto ẹgbẹ́ òṣèlú Republican àti Democratic ń gbèrò báyìí láti wá àtúnṣe pàápàá lórí ìpalára tí wọn ní Facebook dá silẹ lọjọ Aje tí gbogbo itakun wọn o ṣíṣẹ.

Dan Sullivan, ọmọ ẹgbẹ́ Republican ni "aye yóò bi wá léèrè pé kí ni a n rò pẹlu awọn àsọtẹ́lẹ̀ tí a gbọ́ nípa ipa tí Facebook ń kó lára àwọn ọmọ ".

Ọrọ ti Zuckerberg fi síta gùn, nínú rẹ kò tọka si Haugen àmọ́ awọn eeyan ya boo. Ohun tó ń gbìyànjú láti ja fun ṣáá ni pé ẹ̀sùn Haugen ko ba ohun táwọn ń ṣe mu rárá.

Zuckerberg gbagbọ pé irinṣẹ ohun rere ní Facebook jẹ.