Mouth odour: Ọ̀nà márùn-ún tí o lè gbà láti ṣẹ́gun ẹnu rírùn àti ìṣòrò eyín

Láti igba ti olukuluku ti wa ni ọmọde lo ti n gbọ pe ẹẹmeeji lojumọ lo yẹ ki eniyan maa fọ eyin.

Ṣugbọn awọn onimọ iṣegun ti ṣalaye ọna ti o le gba gbogun ti isoro eyin didun ati ẹnu rirun, erigi to n ṣẹjẹ ati awọn inira eyin miiran.

Gẹgẹ bi wọn se sọ awọn koko yii ni lati sọna bi eyin awọn eniyan ko se ni maa ra ti yoo si fa iṣoro eyin didun.

a ṣan ẹnu rẹ nu ni kete ti o ba fi ọṣẹ fọyin tan

Ajọ eto ilera lorilede UK (NHS) gba awọn eniyan niyanju pe ti o ba ti fọ ẹnu tan, o le tu ọṣẹ ifọyin rẹ danu ṣugbọn ma ṣan ẹnu rẹ ni kiakia.

Idi eyi ni pe ti o ba ṣan yoo ṣan eroja Floride ti o yé ki o pa kokoro to wa ninu eyin rẹ danu.

Ma fi igi itayin yọ ounjẹ to ba ha sinu eyin rẹ kuro

NHS fi kun imọran rẹ pe, ki enikẹni ma ṣe maa lo igi itayin yọ ounjẹ to ba ha sinu eyin kuro.

Idi eyi ni pe, o le gun erigi ti yoo di egbo ti yoo si fa aisan sinu eyin naa.

Imọran ti wọn fi kun un ni pe ki eniyan lo okun tinrin ti o ba ni eji laarin awọn eyin rẹ lati yọohunkohun to ba ha sibẹ kuro.

Fi okun tinrin yọ idọti lati mu adinku ba ẹnu rirun

Eyi ni ti o ba fi okun tabi owu tinrin si aarin eyin rẹ lati yọ idọti to ba wa nibẹ kuro.

O dara ki eniyan maa lo okun lati yọ idọti kuro ninu eyin rẹ,n itori ajọ NHS sọ pe ti eniyan ba n se eyi deede yoo mu adinku ba awọn aisan to maa n ṣe eyin.

Wọn ni eyi ni yoo yọ gbogbo idọti to wa ninu eyin.

Ma lo omi ifọyin lẹyin ti o ba ti fi ọṣẹ fọyin tan

NHS fi imọran sita pe omi ifọyin lẹyin ti o ba ti fọnu tan, o le ṣe isẹ ti omi naa yoo se lati san gbogbo ọṣẹ ti o fi fọnu kuro lẹnu.

O yẹ ki obi maa ba ọmọ fọ ẹnu rẹ titi di ọdun meje

Lakotan NHS sọ pe o ṣe pataki lati maa ba ọmọ fọnu titi yoo fi pe ọmọ ọdun meje.

Imọran naa ni pe, ti o ko ba le ran lọwọ o yẹ ki o moju too bi o se n fọọ titi ti yoo fi pe ọdun meje