Nigeria Police: Ìgbẹ́jọ́ tẹ̀síwájú lórí ọ̀lọ́pàá tí wọ́n yọ ní iṣẹ́ nítórí ó gboyún láì ṣe ìgbéyàwó

Igbẹjọ tẹsiwaju lọni lori iṣẹlẹ arabinrin Ọmọlola Olajide, ti ileeṣẹ ọlọpaa ni ko lọ rọkun nile nitori o ni oyun lai ṣe igbeyawo.

Olotu eto idajọ nipinlẹ Ekiti, Olawale Dapohunda lo gbẹ Ọga Agba Ọlọpaa lọ si ileẹjọ lori ẹsun pe ki wọn yọ ẹka ofin ileeṣẹ naa to ni ki wọn yọ obinrin to ba ni oyun lai ṣe igbeyawo kuro ni ibi iṣẹ

Ìgbẹ́jọ́ tẹ̀síwájú lórí ọ̀lọ́pàá tí wọ́n yọ ní iṣẹ́ nítórí ó gboyún láì ṣe ìgbéyàwó

Fapohunda ni ẹka iwe ofin ileeṣẹ ọlọpaa (Section 127 of the Police Act and Regulations) to fofin de obinrin lati ṣe igbeyawo ki o to le loyun ko ba ofin Naijiria mu, nitori naa wọn gbọdọ wa atunṣe si.

Laipẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria fi ọwọ osi juwe ile fun arabinrin Olajide lati ipinlẹ Ekiti kuro ni idi iṣẹ rẹ gẹgẹ bi ọlọpaa nitori ko i tii ni ade ori, o si gbe oyun wa si ibi iṣẹ.

''Ohun ti ofin ileeṣẹ ọlọpaa sọ ni pe ileeṣẹ ọlọpaa ni aṣẹ lati yọ oṣiṣẹbinrin to ba gba oyun kuro ni ibi iṣẹ''

''Bakan naa ni obinrin naa ko ni le e pada si ẹnu iṣẹ rẹ ayafi ti Ọga Agba Ileeṣẹ Ọlọpaa ba da pada si ẹnu iṣẹ.''

Awọn iyoku ti wọn tun pe lọ si ileẹjọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa ni kọmiṣọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti to fi mọ ileeṣẹ to n risi ọrọ awọn ọlọpaa ni Naijiria.

Ohun ti wọn tun n bere fun ni aṣẹ ileẹjọ lati maṣe jẹ ki igbeṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa lati yọ arabinrin naa ni iṣẹ kẹṣẹjari.

Amọ, ileeṣẹ ọlọpaa ni arabinrin naa tako ofin ileeṣẹ ọlọpaa to ni ẹni to ba ṣẹṣẹ wọ iṣẹ ti gbọdọ wa nibẹ fun ọdun meji ki o to sẹ igbeyawọ, ko si ti lo ọdun mẹta ki o to bimọ.

Amọ arabinrin naa ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ lai ti pe ọdun kan ni o lọ gba oyun.

Ojo Keje, Oṣu Kẹwaa ni adajọ sun igbẹjọ naa si lati mọ bi ọjọ iwaju obinrin naa yoo ṣe ri lẹnu iṣẹ ọba.